"Ibeere 4- Darukọ díẹ̀ nínú awọn ajọṣepọ ati awọn kata-kara ti o jẹ eewọ?"

"Idahun-"

"1- Irẹjẹ, ninu rẹ si ni: Fifi aleebu ọja pamọ."

"Lati ọdọ Abū Hurayrah - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - kọja nibi okiti ounjẹ kan, o wa ti ọwọ rẹ bọ inu rẹ, ni awọn ọmọnika rẹ ba kan nkan tutu kan, ni o ba sọ pe: «Ki ni eléyìí, irẹ oni ounjẹ?» O sọ pe: Ojo ni o pa a irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun. O sọ pe:" «O o ṣe fi i si oke ounjẹ ki awọn eeyan le ba ri i? Ẹni ti o ba ṣe irẹjẹ kii ṣe ara mi» " Muslim ni o gba a wa.

"2- Riba (Ele): Ninu ẹ ni ki n ya ẹgbẹrun kan ni ọwọ ẹnikan lori pe maa da ẹgbẹrun meji pada fun un."

"Alekun yẹn ni ele ti o jẹ eewọ."

Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: "{Allāhu sì ṣe òwò ṣíṣe ní ẹ̀tọ́, Ó sì ṣe òwò èlé ní èèwọ̀}" "[Sūratul Baqorah: 275]."

"3- Ẹtanjẹ ati Iruju (Aimọ): Gẹgẹ bíi ki n ta wara ti n bẹ ninu ọyan ẹran fun ọ, tabi ẹja ti n bẹ ninu omi ti mi o si tii dẹdẹ rẹ."

"O ti wa ninu hadīth pe: (Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - kọ kuro nibi òwò ẹtanjẹ)" Muslim ni o gba a wa.