"Ibeere 6: Ki ni awọn ìran ifọkantan ati awọn aworan rẹ?"

"Idahun-"

"1- Ifọkantan nibi sisọ awọn iwọ̀ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga."

"Awọn aworan rẹ: Ifọkantan nibi pipe awọn ijọsin bi Irun, ati Zakah, ati Aawẹ, ati Hajj, ati eyiti o yatọ si wọn ninu awọn nkan ti Ọlọhun ṣe ni ọranyan le wọn lori."

"Ifọkantan nibi sisọ awọn iwọ awọn ẹda:"

"Nibi sisọ ijẹ-ọmọluabi awọn eeyan."

"Ati awọn dukia wọn."

"Ati awọn ẹjẹ wọn."

"Ati awọn kọkọ wọn, ati gbogbo nkan ti awọn eeyan ba fi ọkan balẹ si ọ lọdọ lori rẹ."

"Ọba ti ọla Rẹ ga sọ nibi awọn iroyin awọn olujere pe:" "{àwọn t’ó ń ṣọ́ àgbàfipamọ́ wọn àti àdéhùn wọn 8}" [Suuratul-Mu’minuun: 8].