"Idahun- Oun ni kíkàndí mọ́lẹ̀ nibi ṣiṣe iṣẹ oloore ati nkan ti ṣiṣe rẹ jẹ dandan fun ọmọniyan."
"Ati pe ninu iyẹn ni: Ìmẹ́lẹ́ nibi ṣiṣe awọn ọranyan."
"Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe:" "{Dájúdájú àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí ń tan Allāhu, Òun náà sì máa tàn wọ́n. Nígbà tí wọ́n bá dúró láti kírun, wọ́n á dúró (ní ìdúró) òròjú, wọn yó sì máa ṣe ṣekárími (lórí ìrun). Wọn kò sì níí ṣe (gbólóhùn) ìrántí Allāhu (lórí ìrun) àfi díẹ̀ 142}" "[Sūratun Nisā'i: 142]."
"Nitori naa o lẹ́tọ̀ọ́ fun Mu'mini gbigbe imẹlẹ ati aileṣiṣẹ, ati ijokoo tẹtẹrẹ ju silẹ, o si tun lẹ́tọ̀ọ́ fun un igbiyanju nibi iṣẹ ati lilọ bibọ ati ṣiṣe wahala ati gbigba iyanju ninu aye sibi nkan ti yio yọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ninu."