"Ibeere 19: Ṣe alaye nkan ti n jẹ Itẹriba?"

"Idahun- Oun ni ki ọmọniyan o ma maa ri ara rẹ lori awọn eeyan, ki o si ma maa yẹpẹrẹ awọn eeyan, ki o si ma maa kọ ododo."

Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: "{Àwọn ẹrúsìn Àjọkẹ́-ayé ni àwọn t’ó ń rìn jẹ́ẹ́jẹ́ lórí ilẹ̀} " [Suuratul-Furqan: 63]. "Itumọ rẹ ni: Ni àwọn tí wọ́n n tẹrí bá." "- Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tun sọ pe:" "«Ẹnikankan o si nii rẹ ara rẹ silẹ fun Ọlọhun ayaafi ki Ọlọhun gbe e ga» " Muslim ni o gba a wa. "O tun sọ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - pe:" "«Dajudaju Ọlọhun ranṣẹ si mi wipe ki ẹ tẹriba, debi wipe ẹnikankan o nii maa ṣe iyanran lori ẹnikẹni, ẹnikankan o si nii maa tayọ aala lori ẹnikẹni» " Muslim ni o gba a wa.