"Ibeere 12: Darukọ iwa ikunlọwọ?"

"Idahun- Oun naa ni ki awọn eeyan maa ṣe ikunlọwọ laarin ara wọn lori ododo ati daadaa."

"Awọn aworan iṣe ikunlọwọ:"

"Iṣe ikunlọwọ lori dida awọn ẹtọ pada."

"Iṣe ikunlọwọ lori dida alabosi ni ọwọ kọ."

"Iṣe ikunlọwọ lori bibiya bukaata awọn eeyan ati awọn alaini."

"Iṣe ikunlọwọ lori gbogbo daadaa."

" Ima maa ṣe ikunlọwọ lori ẹsẹ ati ṣiṣe suta ati ikọja aala."

Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: "{Ẹ ran ara yín lọ́wọ́ lórí iṣẹ́ rere àti ìbẹ̀rù Allāhu. Ẹ má ṣe ran ara yín lọ́wọ́ lórí (ìwà) ẹ̀ṣẹ̀ àti ìtayọ ẹnu-àlà. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu le (níbi) ìyà.}" "[Sūratul Mā’idah: 2]." "Anabi - ki ikẹ ati ọla maa ba a - sọ pe:" "«Mu’mini si Mu'mini da bii ile ni; ti apakan o maa fun apakan ni agbara» " Wọn fi ẹnu ko le e lori. "Anabi - ki ikẹ ati ọla maa ba a - tun sọ pe:" "«Musulumi ọmọ-ìyá Musulumi ni, ko nii ṣe abosi rẹ, ko si nii fa a kalẹ fun ẹniti yio fi ara ni i, ẹniti o ba si n biya bukaata ọmọ-ìyá rẹ, Ọlọhun a maa biya bukaata tiẹ naa, ẹniti o ba si mu ibanujẹ kuro fun musulumi kan, Ọlọhun a mu kuro fun un ibanujẹ kan ninu awọn ibanujẹ ọjọ igbedide, ẹniti o ba si bo musulumi kan ni aṣiri, Ọlọhun a bo oun naa ni aṣiri ni ọjọ igbedide» " Wọn fi ẹnu ko le e lori.