"Idahun- Ṣíṣe suuru lori itẹle ti Ọlọhun -ti ọla Rẹ ga- "
Ṣíṣe suuru kuro nibi ẹṣẹ "
Ṣíṣe suuru lori kádàrá Ọlọhun to mu inira dani, ati di dupẹ fun Ọlọhun lori gbogbo iṣesi."
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: "{Allāhu sì nífẹ̀ẹ́ àwọn onísùúrù 146}." "[Surah Âl-`Imrân: 146]" "Ati pe Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: " “Eemọ ni fun alamọri olugbagbọ, dajudaju gbogbo alamọri rẹ pátápátá jẹ dáadáa, iyẹn ko si fun ẹnikẹni afi fun olugbagbọ; ti idunnu ba ṣẹlẹ si i o maa dupẹ, ìyẹn si maa lóore fun un, ti inira ba ṣẹlẹ si i o ma ṣe suuru, ìyẹn sì maa jẹ oore fun un. Muslim ni o gba a wa.