"Idahun- Lati ọdọ Umar ọmọ Khataab- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Láàrin ìgbátí a jókòó si ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ni ọjọ kan, arakunrin kan yọ si wa ti asọ rẹ funfun gbòò, irun ori rẹ si dudu kirikiri, a o si ri apẹrẹ arìnrìn-àjò lara rẹ, ẹnikankan o si mọ ọn ninu wa, titi ti o fi jókòó ti Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, o wa fi orunkun rẹ mejeeji ti orunkun rẹ (Anabi), o si tun gbe ọwọ rẹ mejeeji le ori itan rẹ mejeeji, o wa sọ pe: «Irẹ Muhammad, fun mi ni iro nipa Isilaamu», o wa sọ fun un pe: «Nkan ti n jẹ Isilaamu ni: ki o jẹrii wipe ko si ẹniti ijọsin ododo tọ si ayaafi Allāhu, ati pe dajudaju Muhammad Ojiṣẹ Rẹ ni, ki o si maa gbe Irun duro, ki o si tun maa yọ Zakah, ki o tun maa gba Aawẹ Ramadan, ki o si tun lọ si Ile Ọlọhun ti o ba kapa ọna atilọ», o sọ pe: «ododo ni o sọ», o waa ya wa lẹnu fun un pe oun ni n bi i leere oun naa ni o tun n fi ododo rẹ rinlẹ, o sọ pe: «Fún mi ni iro nipa ’Īmān (Igbagbọ)», o sọ pe: «ki o ni igbagbọ ninu Ọlọhun, ati awọn Malaika Rẹ, ati awọn Tira Rẹ, ati awọn Ojiṣẹ Rẹ, ati ọjọ ikẹhin, ki o si tun ni igbagbọ ninu kadara, daadaa rẹ ni abi aburu rẹ», o sọ pe: «ododo ni o sọ», o sọ pe: «Fún mi ni iro nipa ’Ihsān», o sọ pe: «ki o maa sin Ọlọhun bi wipe o n ri I, ti o o ba ri I, dajudaju Oun n ri ọ», o sọ pe: «Fún mi ni iro nipa As Sā‘ah (Igbẹyin aye)», o sọ pe: «ki ẹrubinrin o maa bi olowo rẹ, ki o si tun maa ri awọn ti wọn ko nii wọ bàtà, ati awọn arinhoho, ati awọn alaini awọn adaranjẹ, ti wọn a maa kọ awọn ile giga ni ti ìdíje» lẹyin naa ni o wa lọ, mo wa ṣe suuru fun igba diẹ, lẹyin naa, o wa sọ pé: «Irẹ Umar, njẹ o mọ onibeere yẹn?», mo sọ pe: "Ọlọhun ati Ojiṣẹ Rẹ nikan ni wọn ni imọ julọ", o sọ pe: «Jibrīlu ni, o wa ba yin lati fi ẹsin yin mọ yin»" Muslim ni o gba a wa.
"Ninu awọn anfaani inu Hadīth yii:"
1- Didarukọ awọn origun Isilaamu maraarun, awọn naa ni:
"Ijẹrii pe ko si ẹniti ijọsin tọ si l'ododo ayaafi Allāhu, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Rẹ ni"
"Ati gbigbe Irun duro"
"Ati yiyọ Zakah"
"Ati gbigba aawẹ Ramadan"
"Ati ṣíṣe hajj lọ si ile Ọlọhun abeewọ"
2- Didarukọ awọn origun igbagbọ, mẹfa ni:
"Nini igbagbọ ninu Ọlọhun"
"Ati awọn malaika Rẹ"
"Ati awọn tira Rẹ"
"Ati awọn ojiṣẹ Rẹ"
Ati ọjọ ikẹyin."
Ati kadara, eyi ti o daa nibẹ ati eyi ti o buru nibẹ."
"3- Didarukọ origun ṣíṣe dáadáa, origun kan ni, oun ni ki o maa jọsin fun Ọlọhun gẹgẹ bii pe o n ri I, ti o o ba ri I, dajudaju Oun n ri ẹ."
"4- Asiko ọjọ igbedide, ko si ẹni kan kan ti o ni imọ nipa ẹ afi Ọlọhun -ti ọla Rẹ ga-. "
"Hadisi ẹlẹẹkẹrin: "