"Ibeere ẹlẹẹkẹtala: Parí hadiisi: “Ninu didara Isilaamu ọmọniyan...”, ki o si darukọ diẹ ninu awọn anfaani ẹ?"

Idahun- lati ọdọ Abu Hurayra -ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: " “Ninu dida Isilaamu ọmọniyan: Ni ki o maa gbe nnkan ti ko ba kan an ju silẹ”. "Tirmidhi ati ẹni ti o yatọ si i ni wọn gba a wa.

"Ninu awọn anfaani to wa ninu hadiisi naa: "

"1- Gbigbe nnkan ti ko ba kan eniyan ju silẹ ninu awọn alamọri ẹsin ẹlomiran ati aye rẹ. "

"2- Ki o gbe nnkan ti ko kan an ju silẹ wa ninu pipe ẹsin rẹ. "

"* Hadiisi kẹrinla: "