"Idahun- Suratul A'diyah ati alaye ẹ:
Bismillah hir Rahman nir Raheem
{Wal’aadi yaati dabha 1 " "{Fal mooriyaati qadha 2 " "{Fal mugheeraati subha 3 " "{Fa atharna bihii naq’a 4 " "{Fawasatna bihii jam’a 5 " "{Innal-insaana lirabbihii lakanood 6 " "{Wa innahu ‘alaa zaalika la shaheed 7 " {Wa innahu lihubbil khairi la shadeed 8 " "{Afala ya’lamu iza b’uthira ma fil kubuur 9 " "{Wa hussila maa fis suduur 10 " {Inna rabbahum bihim yauma ‘izin lakhabeer 11} " [Sūratul ‘Ādiyāt: 1 - 11].
Alaye:
1- {Wal ‘ādiyāti dọbhā 1}: Ọlọhun bura pẹlu awọn ẹṣin ti wọn maa n sare debi wipe wọn a maa gbọ ohun eemi wọn latari lile ere sisa naa.
2- {Fal mūriyāti qad’hā 2}: O si tun bura pẹlu awọn ẹṣin ti awọn patako ẹsẹ wọn maa n sa ina nígbà tí wọn ba tẹ apata látàrí lile titẹ ẹ wọn.
3- {Fal mugīrāti subhā 3}: O si tun búra pẹlu awọn ẹṣin tii maa n kọlu awọn ọta ni aarọ.
4- {Fa ’atharna bihi naq‘ā 4}: Ti wọn ta eruku lala pẹlu ere sisa wọn.
5- {Fa wasatna bihi jam‘ā 5}: Wọn si tun bẹ gija papọ pẹlu awọn afẹsinjagun wọn si aarin awọn ọta.
6- {Innal insāna li Robbihi la kanūd 6}: Dajudaju ọmọniyan ẹniti maa n kọ daadaa ti Oluwa rẹ n fẹ lati ọdọ rẹ ni.
7- {Wa innāhu ‘alā dhālika la shahīd 7}: Ati pe dajudaju oun naa n jẹrii lori kikọ daadaa rẹ (ṣiṣe aimoore rẹ).
8- {Wa innāhu li hubbil khayri la shadīd 8}: Ati pe dajudaju latari ifẹ afẹju rẹ si owo, yio maa ṣe ahun pẹlu rẹ.
9- {Afalā ya‘lamu izaa bu‘thira mā fil qubūr 9}: Ṣe ọmọniyan ti n gba ẹtan pẹlu isẹmi aye o wa mọ wipe nígbà tí Ọlọhun ba gbe nkan ti o wa ninu ilẹ ni awọn oku jade ti O si tun mu wọn jade lati inu ilẹ fun iṣiro ati ẹsan wipe dajudaju alamọri naa ko ri bi oun ṣe n ro o?.
10- {Wa hussila mā fis suduur 10}: Wọn o ṣe afihan gbogbo nkan ti o wa ninu awọn ọkan ni awọn erongba ati awọn adisọkan ati nkan miran yatọ si i.
11- {Inna Rọbbahum bihim yaoma’idhin la khabīr 11}: Dajudaju Oluwa wọn ni Alamọtan nipa wọn ni ọjọ yẹn, ti nkankan o si nii pamọ fun un ninu alamọri awọn ẹru Rẹ, ti Yio si san wọn ni ẹsan lori iyẹn.