Idahun- Sūratul Masad ati alaye rẹ:
"BismiLlāhir Rahmānir Rahīm"
{Tabbat yadā abī lahabin wa tabba 1" "Mā agnā ‘anhu māluhu wa mā kasaba 2" "Sa yaslaa nāran dhāta lahab 3" "Wamra’atuhu hammālatal hatab 4" "Fī jīdihā hablun min masad 5} "[Sūratul Masad: 1 - 5]"
Alaye
1- {Tabbat yadā abī lahabin wa tabba 1}: Ọwọ mejeeji ọmọ-ìyá baba Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tii ṣe Abu Lahabi ọmọ Abdul Muttalib ti p'ofo latari ipofo iṣẹ rẹ, nitori pe o maa n fi suta kan Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, nitori naa wahala rẹ ja si ofo.
2- {Mā agnā ‘anhu māluhu wa mā kasaba 2}: Ki ni nkan ti dukia ati ọmọ rẹ fi ṣe e ni anfaani? Wọn o lee ti iya danu fun un, bẹẹ si ni wọn o lee fa ikẹ wa fun un.
3- {Sa yaslaa nāran dhāta lahab 3}: Yio si wọ ina eléjò fòfò, ti yoo maa fojú winá ooru rẹ.
4- {Wamra’atuhu hammālatal hatab 4}: Iyawo rẹ Ummu Jamīl naa o wọ ọ (ina), ẹniti o ṣe wipe o maa n ni Anabi lara pẹlu dida ẹgun si oju-ọna rẹ.
5- {Fī jīdihā hablun min masad 5}: Okun kan ti wọn lọ yanjú (daadaa) wa ni orun rẹ ti wọn o fi wọ ọ lọ si inu ina.