Idahun- Sūratul Kaothar ati alaye rẹ:
" BismiLlāhir Rahmānir Rahīm "
{Innā a‘taynākal kaothar 1 " " Fa salli li robbika wanhar 2 " " Inna shāni’aka huwal ’abtar 3} " [Suuratul-Kawthar: 1-3].
Alaye
1- {Innā a‘taynākal kaothar 1}: Dajudaju Awa ni A fun ọ - irẹ Ojiṣẹ - ni oore ti o pọ, ninu rẹ naa si ni abata Kaothar ninu al-Jannah.
2- {Fa salli li robbika wanhar 2}: Nitori naa dúpẹ́ fun Ọlọhun rẹ lori idẹra yii, pẹlu ki o kirun fun Un ki o si pa ẹran fun Un ni Oun nikan ṣoṣo, yatọ si nkan ti awọn ọṣẹbọ maa n ṣe nibi imaa wa asunmọ awọn oriṣa wọn pẹlu pipa nkan fun wọn.
3- {Inna shāni’aka huwal ’abtar 3}: Dajudaju ẹniti ba n binu rẹ (korira rẹ) oun ni ẹniti o ja kuro nibi gbogbo daadaa, ẹni igbagbe ti o ṣe wipe ti wọn ba ranti rẹ wọn o ranti rẹ pẹlu aburu ni.