Ibeere 10: Ka Sūratul Mā‘ūn ki o si ṣe alaye rẹ?

Idahun- Sūratul Mā‘ūn ati alaye rẹ:

"BismiLlāhir Rahmānir Rahīm"

"{Ara’aytal ladhī yukaddhibu bid dīn 1" "Fa dhālikal ladhī yaduhhul yatīm 2" "Walā yahuddu ‘alā ta‘āmil miskīn 3" "Fa waylun lil musọlliin 4" "Allādhīna hum ‘an sọlaatihim sāhūn 5" "Alladhīna hum yurā’ūn 6" "Wa yamna‘ūnal mā‘ūn 7}" "[Sūratul Mā‘ūn: 1 - 7].

Alaye:

1- {Ara’aytal ladhī yukaddhibu bid dīn 1}: Njẹ o mọ ẹni tí maa n pe ẹsan ti ọjọ Igbedide ni irọ.

2- {Fa dhālikal ladhī yaduhhul yatīm 2}: Oun ni ẹni naa ti maa n fi agbara le ọmọ orukan danu kuro nibi gbigbọ bukaata rẹ.

3- {Walā yahuddu ‘alā ta‘āmil miskīn 3}: Ko si ki n ṣe ẹmi rẹ ni ojukokoro, ko si tun ki n ṣe ẹlomiran ni ojukokoro lori fifun alaini ni ounjẹ.

4- {Fa waylun lil musalliin 4}: Nitori naa iparun ati iya ko maa bẹ fun awọn kirunkirun.

5- {Allādhīna hum ‘an salaatihim sāhūn 5}: Awọn ti wọn maa n gbagbera kuro nibi Irun wọn, ti wọn o si ki n bikita pẹlu rẹ titi ti asiko rẹ o fi lọ.

6- {Alladhīna hum yurā’ūn 6}: Awọn ti wọn maa n ṣe ṣekarimi pẹlu Irun wọn ati awọn iṣẹ wọn, wọn o si ki n mọ iṣẹ kanga fun Ọlọhun.

7- {Wa yamna‘ūnal mā‘ūn 7}: Wọn o si maa kọ lati ṣe iranlọwọ fun ẹni tí o yatọ si wọn pẹlu nkan ti ko si inira kankan nibi ṣiṣe iranlọwọ pẹlu rẹ.