Ibeere 28: Ewo lo ni ọla ju ninu awọn ọjọ ọsẹ?

Idahun- Ọjọ Jumu‘ah, Anabi - ki ikẹ ati ọla maa ba a - sọ pe: «Dajudaju ninu awọn ọjọ yin to daa julọ ni ọjọ Jumu‘ah, ninu ẹ ni wọn da Ādam, ninu ẹ ni wọn gba ẹmi rẹ, ninu ẹ feere fifun o ti waye, ninu ẹ ni kiku (gbogbo ẹda) o ti waye; nitori naa ẹ pọ ni ṣiṣe assalātu fun mi ninu ẹ; nítorí pé dajudaju wọn yio maa fi assalātu yin han mi» O sọ pe: Wọn sọ pe irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, bawo ni wọn o ṣe maa fi awọn assalātu wa han ọ ti o si jẹ wipe o ti kẹfun - nkan ti wọn n sọ ni pe o ti jẹra - o wa sọ pe: «Dajudaju Ọlọhun - ti O biyi ti O si tun gbọnngbọn - ti ṣe awọn ara awọn Anabi Rẹ ni eewọ fun ilẹ». Abu Daūd ati ẹlomiran yatọ si i ni wọ́n gba a wa.