"Ibeere ẹlẹẹkarundinlọgbọn: Báwo ni musulumi ṣe maa kirun? "

"Idahun- bi a ṣe n kirun: "

"1- Didojukọ qiblah pẹlu gbogbo ara rẹ, láìní yẹ̀ tabi yíjú. "

"2- Lẹyin naa yoo dàníyàn irun ti o fẹ ki pẹlu ọkan rẹ laini wi aniyan naa jáde. "

"3- Lẹyin naa yoo kabara iwọ irun, yio sọ pe: (Allahu Akbar), yio gbe ọwọ rẹ mejeeji soke titi de ejika rẹ mejeeji nibi kikabara. "

4- Lẹyin naa yio gbe atẹlẹwọ ọtun rẹ lori ẹyin atẹlẹwọ osi rẹ lori aya rẹ.

5- Lẹyin naa yio bẹrẹ Irun lẹniti yio maa sọ pe «Allāhumma bā‘id baynī wa bayna khatāyāya kamā bā‘adta baynal mashriq wal Magrib, allāhumma naqqinī min khatāyāya kamā yunnaqqa thaobul abyadu minad danas, allāhumma igsilnī min khatāyāya bil mā’i wath-thalji wal barad».

Tabi ki o sọ pe: «Subhānaka allāhumma wa bi amdika, wa tabāraka ismuka wa ta‘ālā jadduka, wa lā ilāha gayruka».

6- lẹyin naa yio wa iṣọra ti yio si maa sọ pe: «A‘ūdhu billāhi minash Shaytānir rajīm». 7- Lẹyin naa yio ṣe bismiLlāhi yio si ka Fātiha ti yio maa sọ pe: "BismiLlāhir Rahmānir Rahīm" 1 "Alhamdulillāhi robbil aalamiin" 2 "Ar-Rahmānir Rahīm" 3 "Māliki yaomid dīn" 4 "Iyyāka na‘budu wa iyyāka nasta‘īn" 5 "Ihdinas Sirātal mustaqiim" 6 "Sirātal Ladhīna an‘amta ‘alayhim gayril magdūbi ‘alayhim walad dālīn" 7 Sūratul Fātiha: 1-7.

Lẹyin naa yio sọ pe: (Āmīn) itumọ rẹ ni wipe: Irẹ Ọlọhun jẹ ipe.

8- Lẹyin naa yio ka eyikeyi ti o ba rọ ọ lọrun ninu Al-Qur'āni, yio si fa kika nkan gun nibi Irun Subhi".

9- Lẹyin naa yio rukuu, iyẹn tumọ si wipe: Yoo tẹ ẹyin rẹ lati gbe titobi fun Ọlọhun, yio si kabara nígbà tí o ba fẹ rukuu, ti yio si gbe ọwọ rẹ mejeeji si deedee ejika rẹ mejeeji. Àti pé sunnah ni: Ki o na ẹyin rẹ, ki o si fi ori rẹ ṣe deedee rẹ, yio si tun gbe ọwọ rẹ mejeeji le orunkun rẹ mejeeji l'ẹniti yio ya awọn ọmọnika ọwọ.

10- Yio si tun sọ nibi rukuu rẹ pe: «Subhāna robbiyal adhīm» ni ẹẹmẹta, ti o ba wa fi kun un pe: "Subhānaka allāhumma wa bi amdik, allāhumma igfir li», ìyẹn náà dáa.

11- Lẹyin naa yio gbe ori rẹ soke lati rukuu lẹniti yio maa sọ pe: «Sami‘a Llāhu liman hamidahu» ti yio si gbe ọwọ rẹ mejeeji si deedee ejika rẹ mejeeji. Ẹniti o jẹ ero ẹyin (ti n kirun lẹyin Imāmu) o nii sọ pe: «Sami‘a Llāhu liman hamidahu» bi ko ṣe pe yio sọ lati fi jirọ rẹ pe: «Rabbanā walakal amdu»

12- Lẹyin naa yio wa sọ lẹyin ti o ba ti gbe ori soke pe: «Rabbanā wa lakal amdu mil’as samāwāti wal ardi, wa mil’a mā shita min shay’in ba‘d».

13- Lẹyin naa yio ṣe iforikanlẹ àkọ́kọ́, yio waa maa sọ nígbà tí o ba fẹ fi orikanlẹ rẹ pe: “Allāhu Akbar” ti yio si fi oríkèé ara meje kanlẹ: Iwaju ori ati imu, atẹlẹwọ mejeeji, orunkun mejeeji, ati awọn ọmọnika ẹsẹ mejeeji, yio si gbe apa rẹ mejeeji jina si ẹgbẹ rẹ, ko si nii tẹ apa rẹ mejeeji silẹ, ti yio si tun da oju awọn ọmọnika ẹsẹ rẹ mejeeji kọ Qibla.

14- Yio waa maa sọ ni iforikanlẹ pe: «Subhāna robbiyal a’lā» ni ẹẹmẹta, ti o ba si tun fi kun un pe: «Subhānaka allāhumma robbāna wa bi amdika, allāhumma igfir lii» o daa.

15- Lẹyin naa yoo gbe ori soke lati iforikanlẹ lẹniti yio maa sọ pe: “Allāhu Akbar”.

16- Lẹyin naa yio jókòó laarin iforikanlẹ mejeeji lori ẹsẹ osi rẹ ti yio si na ẹsẹ ọtun rẹ, ti yio si gbe ọwọ ọtun rẹ si eti itan rẹ ọtun ti o tẹle orunkun, yio waa ka ìka oruka-yẹmi ati kurumbete kò, yio waa na ìka odun-unlabẹ rẹ soke ti yio si maa mi in nibi adua, ti yio si fi eti atampako rẹ ko eti ogajuwọnlọ gẹ́gẹ́ bíi òrùka róbótó, yio waa gbe ọwọ́ rẹ osi lori eti itan òsì rẹ ti o sunmọ orunkun ni ẹni tí yio tẹ́ awọn ọmọnika rẹ silẹ.

17- Yio si tun sọ nibi ìjókòó rẹ laarin iforikanlẹ mejeeji pe: «Robbi igfir lī, warhamnī, wahdinī, warzuqnī, wajburnī, wa ‘āfinī».

18- Lẹyin naa yio ṣe iforikanlẹ ẹlẹẹkeji gẹgẹ bii àkọ́kọ́ nibi nkan ti wọn n sọ ti wọn si maa n ṣe nibẹ, yio si kabara nibi iforikanlẹ rẹ.

19- Lẹyin naa yio dide nibi iforikanlẹ ẹlẹẹkeji lẹniti yio maa sọ pe: «Allāhu Akbar» yio si ki rakah ẹlẹẹkeji bíi àkọ́kọ́ nibi nkan ti wọn n sọ ti wọn si maa n ṣe nibẹ, ṣùgbọ́n ko nii sọ adua iṣirun nibẹ.

20- Lẹyin naa yio jókòó ti o ba ti pari raka‘ ẹlẹẹkeji lẹniti yio maa sọ pe: «Allāhu Akbar», yio si tun jókòó gẹgẹ bi o ṣe jókòó laarin iforikanlẹ mejeeji gẹlẹ.

21- Yio si ka ataaya nibi ìjókòó yii, ti yio maa sọ pe: At-Tahiyyātu lillāh was sọlawātu wat Tọyyibāt, As-salaamu alayka ayyuhan nabiyyu warahmatulloohi wabarokaatuh, as’salāmu ‘alaynā wa ‘alā ‘ibādillāhis soolihiin, ’Ashhadu ’an lā ’ilāha ’illāLlāhu, wa ’ashhadu ’anna Muhammadan ‘abduhu wa rọsūluhu, allāhummọ solli ‘alā Muhammadin wa ‘alā āli Muhammadin, kamā sollayta ‘alā ’Ibrāhīm wa ‘alā āli ’Ibrāhim, ’innaka Hamīdun Majīd, wa bārik ‘alā Muhammadin wa ‘alā āli Muhammadin, kamā bārakta ‘alā ’Ibrāhīm wa ‘alā āli ’Ibrāhim, ’innaka Hamīdun Majīd. ’A‘ūdhu bil Lāhi min ‘adhābi jahannam, wa min ‘adhābil qobri, wa min fitnatil mahyā wal mamāti, wa min fitnatil masīhid dajjāl»

"Gbogbo kiki ti Ọlọhun ni, gbogbo Irun ati gbogbo dáadáa tí Ọlọhun ni, ọla Ọlọhun ki o maa ba ọ iwọ Anabi ati ikẹ Rẹ ati awọn oore Rẹ, ọla Ọlọhun ki o maa ba awa naa ati gbogbo awọn ẹrusin Ọlọhun ti wọn jẹ ẹni ire, mo jẹri wipe ki ẹnití ìjọsìn ododo tọ sí ayaafi Allōhu, mo sì tun jẹri wipe Muhammad ẹru Rẹ ni òjíṣẹ Rẹ sì ni pẹlu, Iwọ Oluwa wa ṣe ikẹ fún Anabi Muhammad, ati awọn ara ile Anabi Muhammad, gẹgẹbi O ṣe ṣe ikẹ fún Anabi Ibrōhēm ati awọn ara ile Anabi Ibrōhēm dajudaju Irẹ ni Ọba ẹlẹyin Ọba ti o tobi, Oluwa wa ṣe Ìbùkún fún Anabi Muhammad ati awọn ara ile Anabi Muhammad, gẹgẹbi O ṣe ṣe Ìbùkún fún Anabi Ibrōhēm ati awọn ara ile Anabi Ibrōhēm, dajudaju Irẹ ni Ọba ẹlẹyin Ọba ti o tobi" Lẹyin naa yio wa kepe Oluwa rẹ pẹlu nkan ti o ba fẹ ninu oore aye ati ti ọjọ ikẹhin.

22- Lẹyin naa yio waa salamọ si ọtun rẹ l'ẹniti yio maa sọ pe: «As Salāmu alaykum wa rahmotulloohi», ati osi rẹ bákannáà.

23- Ti Irun ba wa jẹ olopoo mẹta tabi mẹẹrin; yio duro nibi ipari ataaya àkọ́kọ́, oun naa ni: «’Ashhadu ’an lā ’ilāha ’illāLlāhu, wa ’ashhadu ’anna Muhammadan ‘abduhu wa rọsūluhu»

24- Lẹyin naa yio waa dide duro l'ẹniti yio maa sọ pe: «Allāhu Akbar», ti yio si gbe ọwọ rẹ mejeeji si deedee ejika rẹ mejeeji nígbà náà.

25- Lẹyin naa yio ki èyí tí o ṣẹku nibi Irun rẹ lori iroyin rakah ẹlẹẹkeji, ṣùgbọ́n Fātiah nikan ni yio ka.

26- Lẹyin naa yio jókòó ni ìjókòó tawarruk, ti yio gbe ẹsẹ ọtun rẹ soke, yio si yọ ẹsẹ osi rẹ jade labẹ ojugun rẹ ọtun, ti yio si fi idi rẹ le'lẹ dáadáa, yio waa gbe ọwọ rẹ mejeeji lori itan rẹ mejeeji lori iroyin bi o ṣe gbe e nibi ataaya àkọ́kọ́.

27- Yio waa ka gbogbo ataaya nibi ìjókòó yii.

28- Lẹyin naa yio wàá salamọ si ọtun rẹ l'ẹniti yio maa sọ pe:: «As Salāmu alaykum wa rahmotulloohi», ati osi rẹ bákannáà.