Idahun- Mẹrinla ni i, gẹ́gẹ́ bí o ṣe n bọ̀ yii:
Akọkọ rẹ: Diduro níbi Irun ọranyan fun ẹniti o ni ikapa.
Kabara imura, oun naa ni: “Allāhu Akbar”.
Kika Fātiah.
Itẹkọkọ, yio wàá na ẹyin rẹ tọọ ti yio si gbe ori rẹ si deedee rẹ.
Gbigbe ori kuro nibẹ (Itẹkọkọ).
Diduro dede.
Iforikanlẹ, gbigbe iwaju ori rẹ, ati imu rẹ, ati atẹlẹwọ rẹ mejeeji, ati orunkun rẹ mejeeji, ati awọn ọmọnika ẹsẹ rẹ mejeeji le aaye iforikanlẹ rẹ daadaa.
Gbigbe ori kúrò ni iforikanlẹ.
Ìjókòó laarin iforikanlẹ mejeeji.
Sunnah ni: Ki o jókòó ni ẹniti yio tẹ ẹsẹ osi rẹ silẹ, ti yio si na ẹsẹ ọtun rẹ duro, ti yio si da a kọ Qibla.
Ifarabalẹ, oun naa ni isinmi ara nibi gbogbo orígun ti o jẹ iṣẹ ṣiṣe.
Ataaya Igbẹyin.
Jíjókòó fun un (Ataaya igbẹyin).
Salamọ Mejeeji, oun naa ni ki o sọ ni ẹẹmeji pe: “As salāmu alaykum wa rahmotulloohi wa barakaatuhu”.
Tito awọn orígun tẹle ara wọn- gẹ́gẹ́ bí a ti wi - ti o ba wa fi orikanlẹ ṣíwájú ki o to rukuu lẹniti o mọ̀ọ́mọ̀ ṣe e; o (Irun) ti bajẹ, ti o ba wa jẹ ti igbagbe; o jẹ dandan fun un pipada lati lọ rukuu, lẹyin naa ki o wa fi ori kanlẹ.