"Ibeere ẹlẹẹkẹjọ: Kí ni o n jẹ ijọsin? "

"Idahun- Oun ni orukọ kan to ko gbogbo nnkan ti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ rẹ ati nnkan ti O yọnu si ninu awọn ọrọ ati iṣẹ ti o pamọ ati èyí tí o han sinu."

"Eyi to han: Gẹgẹ bii iranti Ọlọhun pẹlu ahọn ninu iṣe afọmọ, ati idupẹ, ati igbe Ọlọhun tobi, ati kiki irun ati ṣiṣe Hajj. "

"Eyi to pamọ: Gẹgẹ bii igbarale Ọlọhun ati ibẹru ati agbiyele. "