"Ibeere ẹlẹẹkejilelogoji: Àwọn wo ni Ahlus Sunna Wal Jamaa’ah?"

"Idahun- awọn ni awọn to wa lori nnkan ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa lori ẹ ati awọn sàábé rẹ nibi ọrọ ati iṣẹ ati adisọkan. "

"Wọn sọ wọn ni oni sunnah: Torí itẹle wọn ti wọn n tẹle oju-ọna Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ati gbigbe adadaalẹ ju silẹ. "

"Wal Jamaa'ah: Torí pe wọn kojọ lori ododo ti wọn ko si yapa nibẹ.