Idahun- ALLAAHU: Ìtumọ̀ rẹ ni pe Ọba ti a n sin ni ododo, Oun nikan ni O da wa ti ko si ni akẹgbẹ.
AR-ROBB: Ìtumọ̀ rẹ ni Oludẹdaa, Olukapa, Olupese, Oluṣeto ni Oun nikan ṣoṣo, mimọ fun Un.
AS-SAMIIHU: Ẹni tí igbọran Rẹ kari gbogbo nnkan, O si n gbọ gbogbo ohun tòun ti bi o ṣe pe oríṣiríṣi.
AL-BASIIR: Ẹni tí O ṣe pe O n ri gbogbo nnkan, O si n ri gbogbo nnkan boya o kere ni tabi o tobi.
AL-HALIIM: Oun ni imọ Rẹ kari gbogbo nnkan lori ohun ti o ti lọ tabi ti n ṣẹlẹ lọwọ tabi ti yoo pada ṣẹlẹ lọjọ iwaju.
AR-RAHMAAN: Ẹni tí O ṣe pe ikẹ Rẹ kari gbogbo ẹda Rẹ ati gbogbo nǹkan ti n ṣẹmi, gbogbo ẹrusin ati ẹda ni n bẹ labẹ ikẹ Rẹ.
AR-ROZZAAQ: Ọba ti ijẹẹmu gbogbo ẹda ninu eeyan, alijannu ati gbogbo ẹranko n bẹ ni ọwọ Rẹ.
AL-HAYY: Alaaye ti ko nii ku, gbogbo ẹda ni yoo si ku.
"Ọba Ńlá: Ẹni ti O jẹ pe gbogbo pipe nbẹ fun Un ati gbogbo titobi nibi awọn orukọ Rẹ ati awọn iroyin Rẹ ati awọn iṣẹ Rẹ."