Ibẹru: Oun ni bibẹru Ọlọhun ati iya Rẹ.
Ṣíṣe agbiyele: Oun ni ṣiṣe agbiyele ẹsan lọdọ Ọlọhun ati aforijin Rẹ ati ikẹ Rẹ.
Ẹri: Ọ̀rọ̀ Ọlọhun Ọba ti O ga: Àwọn wọ̀nyẹn tí wọ́n ń pè (lẹ́yìn Rẹ̀) ń wá àtẹ̀gùn sọ́dọ̀ Olúwa wọn ni! - Èwo nínú wọn l’ó súnmọ́ (Allāhu) jùlọ (báyìí)? – Àwọn náà ń retí ìkẹ́ Allāhu, wọ́n sì ń páyà ìyà Rẹ̀. Dájúdájú ìyà Olúwa rẹ jẹ́ ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún. 57 [Suuratul-Israa: 57]. Allah tun sọ pe: Fún àwọn ẹrúsìn Mi ní ìró pé dájúdájú Èmi ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run. 49 Àti pé dájúdájú ìyà Mi ni ìyà ẹlẹ́ta-eléro 50 [Suuratul-Hijr: 49, 50].