"Ibeere ẹlẹẹkẹtalelogun: Ta ni opin awọn Anabi ati awọn Ojiṣẹ? "

"Idahun- oun ni Muhammad (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a). "

Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: "{(Ànábì) Muhammad kì í ṣe bàbá ẹnì kan kan nínú àwọn ọkùnrin yín, ṣùgbọ́n (ó jẹ́) Òjíṣẹ́ Allāhu àti òpin àwọn Ànábì...} " [Suuratul-Ahzaab: 40]. "- Ojiṣẹ Ọlọhun -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: " «Emi ni opin awọn Anabi, ko si Anabi kankan lẹyin mi» " "Abu Daud ati Tirmidhi ati ẹni ti o yatọ si wọn ni wọ́n gba a wa. "