"Idahun- "
"1- Sọbẹ-ṣelu nla: Oun ni fifi aigbagbọ pamọ ati ifi igbagbọ han. "
"Yio maa mu ni kuro ninu Isilaamu, o wa ninu aigbagbọ nla. "
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: "{Dájúdájú àwọn ṣọ̀be-ṣèlu mùsùlùmí yóò wà nínú àjà ìsàlẹ̀ pátápátá nínú Iná. O ò sì níí rí alárànṣe kan fún wọn 145} "[Suuratun Nisaa: 145]"
"2- Sọbẹ-ṣelu (Oju eji) kekere: "
"Gẹgẹ bii: Irọ ati iyapa adehun ati ijanba afọkantan. "
"Ko nii mu ni kuro ninu Isilaamu, o wa ninu awọn ẹṣẹ ati pe ẹni ti o n ṣe e maa lẹ́tọ̀ọ́ si iya. "
"Ojiṣẹ Ọlọhun -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: " Àmì ti a fi n da munafiki mọ mẹta ni: Ti o ba sọrọ yóò parọ, ti o ba ṣe àdéhùn yóò yapa, ti wọn ba gbára le e yóò jamba "Bukhari ati Muslim ni wọn gba a wa. "