"Ibeere ẹlẹẹkọkanlelogun: Aigbagbọ a maa jẹ pẹlu ọrọ ati ìṣẹ ati adisọkan, mu àpẹrẹ wa fun iyẹn? "

"Idahun- Àpẹrẹ ọrọ: Bibu Ọlọhun -mimọ ni fun Un- tabi Ojiṣẹ Rẹ -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-."

"Àpẹrẹ iṣẹ: Yiyẹpẹrẹ Kuraani tabi fifi ori kanlẹ fun ẹni ti o yatọ si Ọlọhun -ti ọla Rẹ ga- "

"Àpẹrẹ adisọkan: Didi adisọkan pe nnkankan n bẹ ti o lẹ́tọ̀ọ́ si ijọsin yatọ si Allahu -ti ọla Rẹ ga- tabi pe adẹda kan nbẹ pẹlu Allahu -ti ọla Rẹ ga-. "