Idahun- Al-Walā’u: Oun ni nini ifẹ awọn onigbagbọ ododo ati ṣiṣe iranwọ fun wọn.
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: {Àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, apá kan wọn lọ̀rẹ́ apá kan...}. [Suuratu At-Tawbah: 71].
Al-Barāhu: Oun ni ikorira awọn alaigbagbọ ati iba wọn ṣọta.
Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: Dájúdájú àwòkọ́ṣe rere ti wà fun yín ní ara (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti àwọn t’ó wà pẹ̀lú rẹ̀. Nígbà tí wọ́n sọ fún ìjọ wọn pé: "Dájúdájú àwa yọwọ́-yọsẹ̀ kúrò nínú ọ̀rọ̀ yín àti ohun tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu. A takò yín. Ọ̀tá àti ìkórira sì ti hàn láààrin wa títí láéláé àyàfi ìgbà tí ẹ bá tó gbàgbọ́ nínú Allāhu nìkan ṣoṣo. [Suuratul-Mumtahina: 4].