Ibeere 18: Ki ni a n pe ni adadaalẹ? Ati pe ṣe a maa gba a?

Idahun- Gbogbo nkan ti awọn eeyan ba daalẹ sinu ẹsin, ti ko si si nigba aye Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ati awọn saabe rẹ.

A o nii gba a, ati pe a maa da a pada ni.

Fun ọrọ Anabi - ki ikẹ ati ọla maa ba a - pe: Gbogbo adadaalẹ pata anu ni Abu Daud ni o gba a wa.

Apejuwe rẹ: Alekun nibi ijọsin, gẹ́gẹ́ bíi ṣiṣe alekun fifọ ẹlẹẹkẹrin nibi aluwala, ati ṣiṣe ayẹyẹ ọjọ-ibi Anabi, ko wa lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ati awọn saabe rẹ.