"Idahun- Nini igbagbọ ninu Ọlọhun ti ọla Rẹ ga: "
"Ki o ni igbagbọ pe dajudaju Allahu ni O da ọ ti O si n pese fun ọ, Oun nikan ṣoṣo ni Olukapa ati Oluṣeto gbogbo ẹda. "
"Oun ni Ẹni ti a n jọsin fun, ko si ẹni ti ijọsin ododo tọ si yatọ si I."
"Dajudaju Oun ni Ọba ti O tobi, Ọba nla, Ọba ti O pe julọ ti O ṣe pe gbogbo ọpẹ patapata n jẹ tiRẹ, awọn orukọ to rẹwa ati awọn iroyin to ga n jẹ tiRẹ, ko si orogun fun Un, nnkankan o si jọ Ọ (mimọ ni fun Un). "
" Nini igbagbọ ninu awọn Malaika: "
"Awọn ni ẹda ti Ọlọhun da wọn latara imọle, ati fun ijọsin Rẹ ati fun itẹle to pe fun aṣẹ Rẹ"
"Ninu wọn ni Jibrīl -ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- wa, ẹni ti o ṣe pe o maa n sọkalẹ pẹlu imisi fun awọn Anọbi."
"Nini igbagbọ ninu awọn iwe: "
Awọn ni awọn iwe ti Ọlọhun sọ wọn kalẹ fun awọn Ojiṣẹ Rẹ. "
"Gẹgẹ bii Kuraani: Ti a sọkalẹ fun Muhammad -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-"
"Injīl: Ti a sọkalẹ fun Isa -ki ikẹ Ọlọhun maa ba a-"
"Taorah: Ti a sọkalẹ fun Musa -ki ikẹ Ọlọhun maa ba a-"
"Zabūr: Ti a sọkalẹ fun Dāud -ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- "
Awọn takada Ibrāhīm ati Mūsa: Ti a sọkalẹ fun Ibrohim ati Musa."
Nini igbagbọ si awọn ojiṣẹ [Ọlọhun]
"Awọn ni ẹni ti Ọlọhun ran wọn si awọn ẹru Rẹ lati kọ wọn (ni ẹsin), ati lati fun wọn ni iro idunnu pẹlu daadaa ati alujanna, ati lati ṣe ikilọ fun wọn kuro nibi aburu ati ina. "
"Awọn ti wọn lọla julọ ninu wọn ni: Awọn onipinnu, awọn si ni:
" Nūh -ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- "
" Ibrāhīm -ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- "
Mūsa -ki ikẹ Ọlọhun maa ba a-"
"Ēsa -ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- "
Muhammad -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-."
Nini igbagbọ si ọjọ ikẹyin.
"Oun ni nnkan to wa lẹyin iku ninu sàréè, ati ni ọjọ ajinde, ati ọjọ igbende ati iṣiro, ni ibi ti awọn ero alujanna o ti maa wa ni awọn ibugbe wọn ti awọn ero ina naa o si maa wa ninu awọn ibugbe wọn."
"Nini igbagbọ ninu kadara eyi to daa ninu ẹ ati eyi to buru: "
"Al-Qadar (Kadara): Oun ni nini adisọkan pe dajudaju Ọlọhun ni imọ nipa gbogbo nnkan ti o n ṣẹlẹ ninu aye, ati pe O ti kọ yẹn sinu Laohul Mahfūdh (ọpọn ti A n ṣọ ti akọsilẹ gbogbo nkan wa ninu rẹ), O si tun fẹ bibẹ rẹ ati dida a. "
"Ọba ti ọla Rẹ ga- sọ pe {Dájúdájú A ṣẹ̀dá gbogbo n̄ǹkan pẹ̀lú kádàrá 49}[Surah Al-Qamar: 49]."
" Ipele mẹrin ni o ni: "
"Alakọkọ: Imọ Ọlọhun -ti ọla Rẹ ga-, ninu iyẹn ni imọ Rẹ to ti ṣaaju gbogbo nnkan, ṣíwájú ṣiṣẹlẹ awọn nnkan ati lẹyin ṣiṣẹlẹ rẹ. "
"Ẹri ẹ ni: Ọrọ Ọba ti ọla Rẹ ga-: " Dájúdájú Allāhu, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni ìmọ̀ Àkókò náà wà. Ó ń sọ òjò kalẹ̀. Ó mọ ohun t’ó wà nínú àpòlùkẹ́. Ẹ̀mí kan kò sì mọ ohun tí ó máa ṣe níṣẹ́ ní ọ̀la. Ẹ̀mí kan kò sì mọ ilẹ̀ wo l’ó máa kú sí. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀, Alámọ̀tán. 34 [Suuratu Luqman: 34].
"Ẹlẹẹkeji: Dajudaju Ọlọhun ti kọ yẹn sinu Laohul Mahfūdh (ọpọn ti A n ṣọ ti akọsilẹ gbogbo nkan wa ninu rẹ), ati pe gbogbo nnkan to sẹlẹ ati èyí tí yoo ṣẹlẹ jẹ nnkan ti wọn ti kọ si ọdọ Rẹ sinu iwe "
"Ẹri ẹ ni: Ọrọ Ọba ti ọla Rẹ ga-: " Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àwọn kọ́kọ́rọ́ ìkọ̀kọ̀ wà. Kò sí ẹni t’ó nímọ̀ rẹ̀ àfi Òun. Ó nímọ̀ ohun tí ń bẹ nínú ilẹ̀ àti odò. Ewé kan kò sì níí já bọ́ àfi kí Ó nímọ̀ rẹ̀. Kò sì sí kóró èso kan nínú òkùnkùn (inú) ilẹ̀, kò sí ohun tútù tàbí gbígbẹ kan àfi kí ó wà nínú àkọsílẹ̀ t’ó yanjú. 59 [Suuratul-An’am: 59].
"Ẹlẹẹkẹta: Oun ni pe gbogbo nnkan n ṣẹlẹ pẹlu ifẹ Ọlọhun, nnkankan o nii ṣẹlẹ lati ọdọ Rẹ tabi lati ọdọ ẹda Rẹ afi pẹlu ifẹ Rẹ -Ọba ti ọla Rẹ ga- "
"Ẹri ẹ ni: Ọrọ Ọba ti ọla Rẹ ga-: " "{(Ó wà) fún ẹni tí ó bá fẹ́ nínú yín láti dúró déédé 28 Ẹ̀yin kò sì níí fẹ́ (láti dúró déédé) àyàfi tí Allāhu bá fẹ́, Olúwa gbogbo ẹ̀dá 29} "[Suuratut Takwîr: 28]"
"Ẹlẹẹkẹrin: Nini igbagbọ pe gbogbo nnkan ti o n bẹ ẹda ni wọn ti Ọlọhun da wọn, ti O si da awọn paapaa wọn ati awọn iroyin wọn ati lilọ bibọ wọn, ati gbogbo nnkan ti o n bẹ ninu wọn. "
"Ẹri ẹ ni: Ọrọ Ọba ti ọla Rẹ ga-: " "{Allāhu l’Ó sì dá ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ 96} [Surah As-Sâffât: 96]