"Idahun- 1- Nini igbagbọ ninu Ọlọhun ti ọla Rẹ ga”
"2- Ati awọn Malaika Rẹ."
"3- Ati awọn iwe Rẹ. "
"4- Ati awọn Ojiṣẹ Rẹ."
"5- Ati ọjọ ikẹyin. "
"Ati kadara eyi ti o daa nibẹ ati eyi ti o buru."
"Ẹri ni: Hadisi Jibril ti o gbajumọ lọdọ Muslim, Jibril sọ fun Anọbi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe: " "«Fun mi ni iro nipa igbagbọ, o sọ pe: Ki o ni igbagbọ ninu Ọlọhun, ati awọn Malaika Rẹ, ati awọn iwe Rẹ, ati awọn Ojiṣẹ Rẹ, ati ọjọ ikẹyin, ki o ni igbagbọ ninu kadara eyi ti o daa nibẹ ati eyi ti o buru». "