"Ibeere ẹlẹẹkejila: Darukọ ẹbọ ati awọn iran rẹ?"

"Idahun- Ash-Shirku: Oun ni gbigbe eyikeyi iran ninu awọn iran ijọsin fun ẹlomiran yatọ si Ọlọhun ti ọla Rẹ ga”

"Awọn iran ẹ: "

"Ẹbọ nla; gẹgẹ bii: Pipe ẹni ti o yatọ si Ọlọhun -ti ọla Rẹ ga-, tabi fifi ori balẹ fun ẹni ti o yatọ si I -mimọ fun Un-, abi didu ẹran fun ẹni ti o yatọ si Ọlọhun - ti O lágbára ti O si tun gbọnngbọn-. "

"Ẹbọ kekere; gẹgẹ bii: Bibura pẹlu nǹkan ti o yatọ si Ọlọhun -ti ọla Rẹ ga-, tabi At-Tamā’im (asokọrun), oun naa ni nnkan ti wọn maa n so kọ lati fi fa anfaani wa tabi ti aburu danu, ati eyi to kere ninu ṣekarimi, gẹgẹ bii ki o maa ki irun rẹ dáadáa latari pe o n ri awọn ti wọn n wo o. "