"Ibeere ẹlẹẹkẹwaa: Ki ni awọn iran Taohīd (nini igbagbọ ninu Ọlọhun nikan ṣoṣo)? "

"Idahun-1- Taohīdur Rubūbiyyah: Oun ni nini igbagbọ pe dajudaju Ọlọhun ni Adẹdaa, Olupese, Olukapa, Oluṣeto, ni Oun nikan ṣoṣo ti ko si orogun kankan fun Un. "

"2- Taohīdul 'Ulūhiyyah: Oun ni imu Ọlọhun ni ọkan ṣoṣo pẹlu ijọsin, ti a o si nii jọsin fun ẹnikankan afi Allahu -ti ọla Rẹ ga- "

"3- Taohīdul ’Asmā’i was Sifāt: Oun ni nini igbagbọ ninu awọn orukọ ati awọn iroyin ti Ọlọhun -ti ọla Rẹ ga- ti o wa ninu iwe Ọlọhun ati ọrọ ojiṣẹ Ọlọhun, laisi isafiwe tabi afijọ tabi sisọ pe ko ri bẹẹ. "

"Ẹri awọn iran nini igbagbọ ninu Ọlọhun nikan ṣoṣo mẹtẹẹta ni: ọrọ Ọba ti ọla Rẹ ga - to sọ pe:" {Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. Nítorí náà, jọ́sìn fún Un, kí ó sì ṣe sùúrù lórí ìjọ́sìn Rẹ̀. Ǹjẹ́ o mọ ẹni tí ó tún ń jẹ́ orúkọ Rẹ̀? 65} " [Surah Maryam: 65]"