Ipin Tafsīr

Idahun- Sūratul Fātiha ati alaye rẹ:

"BismiLlāhir Rahmānir Rahīm 1" "Alhamdulillāhi robbil aalamiin 2" "Ar-Rahmānir Rahīm 3" "Māliki yaomid dīn 4" "Iyyāka na‘budu wa Iyyāka nasta‘īn 5" "Ihdinaṣ ṣirātal mistaqīm 6" Sirātọl Ladhīna an‘amta ‘alayhim gayril magdūbi ‘alayhim walad dālīn} Sūratul Fātiha: 1-7.

Alaye

Wọn sọ ọ ni Sūratul Fātiah; latari wipe wọn bẹrẹ iwe Ọlọhun pẹlu rẹ.

1- {BismiLlāhir Rahmānir Rahīm 1} maa bẹrẹ kika Al-Qur'āni mi pẹlu orukọ Ọlọhun, lẹniti n wa iranwọ pẹlu Rẹ lẹniti n wa alubarika pẹlu orukọ Rẹ.

{Allāhu} itumọ rẹ ni: Ẹniti a maa jọsin fun l'ododo, ati pe wọn ki n pe elomiiran bẹẹ yatọ si I- mimọ n bẹ fun un.

{Ar-Rahmān} itumọ rẹ ni wipe: Oni ikẹ ti o gbaaye ti o kari gbogbo nkan.

{Ar-Rọhīm} itumọ rẹ ni wipe: Ẹniti O ni ikẹ fun awọn Mu’mini.

{Alhamdulillāhi robbil aalamiin 2} itumọ rẹ ni pe: Gbogbo iran ẹyin ati pipe ti Ọlọhun ni ni Òun nikan soso.

3- {Ar-Rahmānir Rahīm 3} itumọ rẹ ni pe: Oni ikẹ ti o gbaaye ti o kari gbogbo nkan, Oni ikẹ ti o maa de ọdọ awọn Mu‘mini.

4- {Māliki yaomid dīn 4}: Oun ni ọjọ igbende.

5- {Iyyāk na‘budu wa Iyyāk nasta‘īn 5} itumọ rẹ ni pe: A o maa jọsin fun O ni Iwọ nikan a o si tun maa wa iranwọ Rẹ ni Iwọ nikan.

6- {Ihdinas Sirātal mustaqīm 6}: Oun ni imọna lọ si inu Isilaamu ati Sunnah.

7- {Sirātọl Ladhīna an‘amta ‘alayhim gayril magdūbi ‘alayhim walad dhālīn 7} itumọ rẹ ni pe: Oju-ọna awọn ẹrusin Rẹ ti wọn jẹ ẹni ire ninu awọn Anabi ati awọn ti wọn tẹle wọn, yatọ si ọna awọn Kristẹni ati awọn Júù.

Wọn si tun ṣe e ni sunnah ki o sọ lẹyin kika a pe: (Āmīn) itumọ rẹ ni pe: Jẹ ipe wa (da wa loun).

Idahun- Sūratuz Zalzalah ati alaye rẹ:

"BismiLlāhir Rahmānir Rahīm"

"{Idhā zulzilatil’ardu zilzālahā 1" "Wa ’akhrajatil ’ardu athqālahā 2" "Wa qālal insānu mālahā 3" "Yaoma idhin tuhaddithu akhbārahā 4" "Bi anna robbaka ’aohālahā 5" "Yaoma idhin yasdurun nāsu ashtātan liyurao ’a‘mālahun 6" "Fa man ya‘mal mithqāla dharratin khoyron yarahu 7" Ẹni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ aburú ní òdíwọ̀n ọmọ iná-igún, ó máa rí i 8}." "[Surah Az-Zalzalah: 1 - 8]

Alaye

"1- {Izaa zul zilatil ardu zil zaalaha 1}: ti wọn ba mi ilẹ ni mimi to le koko to jẹ wipe yio sẹlẹ si i ni ọjọ igbedide. "

"2- {Wa akh rajatil ardu athqaalaha 2}: ti ilẹ maa mu nnkan ti o wa ninu ẹ jade ninu awọn oku ati nnkan to yatọ si wọn. "

3- {Wa qaalal insaanu ma laha 3}: eniyan yo si wi pe ni ẹni ti ọrọ o ye: kini o mu ilẹ ti o n mi ti o si n daru?! "

4- {Yawmaa izin tuhaddithu akhbaaraha 4}: ni ọjọ nla yẹn ilẹ o ma sọrọ pẹlu nnkan ti wọn ṣe lori ẹ ninu rere ati aburu."

5- {Bi-anna rabbaka awhaa laha 5}: nitori pe dajudaju Ọlọhun lo fi mọọ ti O si pa a laṣẹ pẹlu iyẹn. "

"6- {Yawma iziny yas durun naasu ash tatal liyuraw a’maalahum 6}: ni ọjọ nla yẹn, eyi to jẹ pe ilẹ ma mi titi nibẹ, ti eniyan o ma jade lati inu aye iṣiro ni ijọ, lati ri awọn iṣẹ wọn eyi to jẹ pe wọn ṣe e ni ile-aye.

7- {Famaiy ya’mal mithqala zarratin khai raiy-yarah 7}: ẹni ti o ba ṣe iṣẹ to to odiwọn awurebe kerere ninu awọn iṣẹ rere ati daada, yo ri i ni iwaju rẹ. "

"8- {Wa maiy-y’amal mithqala zarratin sharraiy-yarah 8}: ẹni ti o ba ṣe iṣẹ ti odiwọn ẹ ninu awọn iṣẹ aburu; yo ri i ni iwaju rẹ. "

"Idahun- Suratul A'diyah ati alaye ẹ:

Bismillah hir Rahman nir Raheem

{Wal’aadi yaati dabha 1 " "{Fal mooriyaati qadha 2 " "{Fal mugheeraati subha 3 " "{Fa atharna bihii naq’a 4 " "{Fawasatna bihii jam’a 5 " "{Innal-insaana lirabbihii lakanood 6 " "{Wa innahu ‘alaa zaalika la shaheed 7 " {Wa innahu lihubbil khairi la shadeed 8 " "{Afala ya’lamu iza b’uthira ma fil kubuur 9 " "{Wa hussila maa fis suduur 10 " {Inna rabbahum bihim yauma ‘izin lakhabeer 11} " [Sūratul ‘Ādiyāt: 1 - 11].

Alaye:

1- {Wal ‘ādiyāti dọbhā 1}: Ọlọhun bura pẹlu awọn ẹṣin ti wọn maa n sare debi wipe wọn a maa gbọ ohun eemi wọn latari lile ere sisa naa.

2- {Fal mūriyāti qad’hā 2}: O si tun bura pẹlu awọn ẹṣin ti awọn patako ẹsẹ wọn maa n sa ina nígbà tí wọn ba tẹ apata látàrí lile titẹ ẹ wọn.

3- {Fal mugīrāti subhā 3}: O si tun búra pẹlu awọn ẹṣin tii maa n kọlu awọn ọta ni aarọ.

4- {Fa ’atharna bihi naq‘ā 4}: Ti wọn ta eruku lala pẹlu ere sisa wọn.

5- {Fa wasatna bihi jam‘ā 5}: Wọn si tun bẹ gija papọ pẹlu awọn afẹsinjagun wọn si aarin awọn ọta.

6- {Innal insāna li Robbihi la kanūd 6}: Dajudaju ọmọniyan ẹniti maa n kọ daadaa ti Oluwa rẹ n fẹ lati ọdọ rẹ ni.

7- {Wa innāhu ‘alā dhālika la shahīd 7}: Ati pe dajudaju oun naa n jẹrii lori kikọ daadaa rẹ (ṣiṣe aimoore rẹ).

8- {Wa innāhu li hubbil khayri la shadīd 8}: Ati pe dajudaju latari ifẹ afẹju rẹ si owo, yio maa ṣe ahun pẹlu rẹ.

9- {Afalā ya‘lamu izaa bu‘thira mā fil qubūr 9}: Ṣe ọmọniyan ti n gba ẹtan pẹlu isẹmi aye o wa mọ wipe nígbà tí Ọlọhun ba gbe nkan ti o wa ninu ilẹ ni awọn oku jade ti O si tun mu wọn jade lati inu ilẹ fun iṣiro ati ẹsan wipe dajudaju alamọri naa ko ri bi oun ṣe n ro o?.

10- {Wa hussila mā fis suduur 10}: Wọn o ṣe afihan gbogbo nkan ti o wa ninu awọn ọkan ni awọn erongba ati awọn adisọkan ati nkan miran yatọ si i.

11- {Inna Rọbbahum bihim yaoma’idhin la khabīr 11}: Dajudaju Oluwa wọn ni Alamọtan nipa wọn ni ọjọ yẹn, ti nkankan o si nii pamọ fun un ninu alamọri awọn ẹru Rẹ, ti Yio si san wọn ni ẹsan lori iyẹn.

Idahun- Sūratul Qāri‘ah ati alaye rẹ:

"BismiLlāhir Rahmānir Rahīm"

"Al-Qāri‘ah 1" "Mal qāri‘ah 2" "Wa mā adrāka mal qāri‘ah 3" "Yaoma yakūnun nāsu kal farāshil mabthūth 4" "Wa takūnul jibālu kal ‘ihnil manfūsh 5" "Fa ammā man thaqulat mawāzīnuhu 6" "Fa huwa fī ‘īshatin rādiyah 7" "Wa ammā man khaffat mawāzīnuhu 8" "Fa ummuhu hāwiyah 9" "Wa mā adrāka mā hiyah 10" "Nārun hāmiyah 11} [Sūratul Qāri‘ah: 1 - 11].

Alaye:

1- {Al-Qāri‘ah 1}: Asiko ti yio maa lu awọn ọkan awọn eniyan latari titobi ibẹru rẹ.

2- {Mal qāri‘ah 2}: Ki ni n jẹ asiko yii ti yio maa lu awọn ọkan awọn eniyan latari titobi ibẹru rẹ?

3- {Wa mā adrāka mal qāri‘ah 3}: Ki lo mu ọ mọ - irẹ Ojiṣẹ - nkan ti n jẹ asiko yii ti yio maa lu awọn ọkan awọn eniyan latari titobi ibẹru rẹ? Dajudaju oun ni ọjọ igbedide.

4- {Yaoma yakūnun nāsu kal farāshil mabthūth 4}: Ọjọ ti yio maa lu awọn ọkan awọn eniyan, wọn o waa da gẹ́gẹ́ bí afopina ti wọn fọnka síhìn-ín sọ́hùn-ún.

5- {Wa takūnul jibālu kal ‘ihnil manfūsh 5}: Ati pe awọn oke o wa da gẹgẹ bii òwú ti wọn fi kùmọ̀ lù ki o le lẹ̀, látara yíyára rẹ.

6- {Fa ammā man thaqulat mawāzīnuhu 6}: Amọ ẹni tí awọn iṣẹ rere rẹ ba tẹsunwọn ju awọn iṣẹ aburu rẹ lọ.

7- {Fa huwa fī ‘īshatin rādiyah 7}: Nitori naa oun o maa bẹ ninu isẹmi kan ti yio yọ ọ ninu ti yio maa ri i ninu aljanna.

8- {Wa ammā man khaffat mawāzīnuhu 8}: Amọ ẹniti awọn iṣẹ aburu rẹ ba tẹsunwọn ju awọn iṣẹ rere rẹ lọ.

9- {Fa ummuhu hāwiyah 9}: Ibugbe rẹ ati ibudo rẹ ni ọjọ Igbedide ni Jahannama.

10- {Wa mā adrāka mā hiyah 10}: Ki ni o mu ọ mọ - irẹ Ojiṣẹ - nkan naa?!

11- {Nārun hāmiyah 11}: Oun ni ina kan ti igbona rẹ le gidi.

Idahun- Sūratut Takāthur ati itumọ rẹ:

"BismiLlāhir Rahmānir Rahīm"

{’Alhākumut takāthur 1" "Hattā zurtumul maqābir 2" "Kallā saofa ta‘lamūn 3" "Thumma Kallā saofa ta‘lamūn 4" "Kallā lao ta‘lamūna ‘ilmal yaqīn 5" "La tarawunnal jahīm 6" "Thumma la tarawunnahā ‘aynal yaqīn 7" " Thumma la tus’alunna yaoma’idhi ‘anin na‘īm 8} "[Sūratut Takāthur: 1 - 8]"

Alaye:

1- {’Alhākumut takāthur 1}: Imaa ṣe iyanran pẹlu awọn dukia ati awọn ọmọ ti ko airoju ba yin - ẹyin eniyan - kuro nibi itẹle Ọlọhun.

2- {Hattā zurtumul maqābir 2}: Titi ti ẹ fi ku ti ẹ si wọ inu awọn sàréè yin.

3- {Kallā saofa ta‘lamūn 3}: Ko yẹ fun yin ki iṣe iyanran yin pẹlu rẹ (awọn dukia ati ọmọ) o ko airoju ba yin kuro nibi itẹle Ọlọhun, ẹ maa pada mọ atunbọtan ikoairoju yẹn.

4- {Thumma Kallā saofa ta‘lamūn 4}: Lẹyin naa ẹ maa mọ atunbọtan rẹ.

5- {Kallā lao ta‘lamūna ‘ilmal yaqīn 5}: Ododo ni ka ni pe ẹ mọ ni amọdaju wipe wọn yio gbe yin dide si ọdọ Ọlọhun, ati pe Yio san yin ni ẹsan awọn iṣẹ yin, ẹ ko nii ko airoju pẹlu imaa ṣe iyanran pẹlu awọn dukia ati awọn ọmọ yin.

6- {La tarawunnal jahīm 6}: Mo fi Ọlọhun bura ẹ maa ri ina ni ọjọ Igbedide.

7- {Thumma la tarawunnahā ‘aynal yaqīn 7}: Lẹyin naa ẹ maa ri i ni riri ti o daju ti ko si iyemeji nibẹ.

8- {Thumma la tus’alunna yaoma’idhin ‘anin na‘īm 8}: Lẹyin naa Ọlọhun o maa bi yin leere ni ọjọ yẹn nipa nkan ti o fi ṣe idẹra le yin lori ninu alaafia ati ọrọ ati nkan miran yatọ si mejeeji.

Idahun- Sūratul Asri ati alaye rẹ:

"BismiLlāhir Rahmānir Rahīm"

{Wal Asri 1 " "Innal insāna lafī khusri 2" "Illāl Ladhīna ’āmanū wa ‘amilus sālihāti wa tawāsao bil haqqi watawāsao bis sobr 3}" [Suuratul-Asr: 1-3].

Alaye:

1- {Wal Asri 1}: Ọba ti mimọ n bẹ fun bura pẹlu igba.

2- {Innal insāna lafī khusri 2}: itumọ rẹ ni pe: Gbogbo eeyan n bẹ ninu adinku ati iparun.

3- {Illāl Ladhīna ’āmanū wa ‘amilus soolihaat wa tawāṣao bil haqqi watawāṣao biṣ ṣobr 3}: Ayaafi ẹniti o ba ni igbagbọ ti o si tun ṣe iṣẹ rere, pẹlu iyẹn wọn tun pepe lọ si idi ododo ti wọn si tun ṣe suuru lori rẹ, nitori naa awọn wọnyii ni wọn ti la kuro ninu ofo.

Idahun- Sūratul Humazah ati alaye rẹ:

"BismiLlāhir Rahmānir Rahīm"

"{Wailul-likulli humazatil-lumazah 1 " "Allazee jama’a maalan wa ‘addadah 2 " "Yahsabu anna maalahuu akhladah 3 " "Kallaa; layumbazanna fil hutamah 4 " "Wa maa adrọọka mal-hutọma 5 " "Naarul Lọọhil mu'kọdah 6 " "Allatii tattọlihu ‘alal af’hidah 7 " "Innahaa ‘alaihim muh’sọdah 8 " "Fii ‘amadim mumaddadah 9} " [Surah Al-Humazah 1 - 9]. "

"Alaye: "

"1- {Wailul-likulli humazatil-lumazah 1}: Àtúbọ̀tán to buru ati iya to le koko n bẹ fun ẹni ti o pọ ni ọrọ-ẹyin fun àwọn eeyan ati biba wọn jẹ. "

"2- {Allazee jama’a maalan wa ‘addadah 2}: Ẹni ti o jẹ pe ironu rẹ ni kiko owo jọ ati kika a, ko si ironu miiran fun un yatọ si iyẹn. "

3- {Yahsabu anna maalahooo akhladah 3}: Ti o n ro pe dajudaju owo rẹ eyi to jẹ pe o kojọ pe yio la a kuro nibi iku, ti yo wa maa ṣe gbere ni isẹmi aye. "

"4- {Kallaa; layumbazanna fil hutamah 4}: Ọ̀rọ̀ kii ṣe bi alaimọkan yii ṣe ro, dajudaju wọn maa ju u sinu ina jahannamọ eyi ti o maa n run gbogbo nnkan ti wọn ba ju síbẹ̀ nitori ilekoko agbara to n bẹ fun un. "

"5- {Wa maa adraaka mal-hutamah 5}: Ki ni o mu ọ mọ̀ -iwọ Ojiṣẹ- ki ni ina yii to jẹ pe o maa n run gbogbo nnkan ti wọn ba ju síbẹ̀?! "

"6- {Naarul laahil-mooqada 6}: Dajudaju oun ni ina Ọlọhun ti o n jò geregere"

"7- {Allatee tattali’u ‘alal af’idah 7}: Èyí to jẹ pe o maa n ti inú ara àwọn èèyàn bọ sinu awọn ọkan wọn. "

"8- {Innahaa ‘alaihim mu’sada 8}: Dajudaju wọn maa ti i mọ awọn ti a n fi iya jẹ. "

"9- {Fee ‘amadin mumaddadah 9}: Pẹ̀lú àwọn òpó kìrìbìtì ti wọn gùn ti wọn ko fi nii le jáde kúrò nibẹ.

"Idahun- Suuratul Fiil ati alaye ẹ: "

"Bismillah hir Rahman nir Raheem "

"{Alam tara kaifa fa’ala rabbuka bi as’haabil feel 1 " "Alam yaj’al kaidahum fee tadleel 2 " "Wa arsala ‘alayhim tayran ’abābīl 3" "Tarmīhim bi hijāratim min sijjīl 4" " Fa ja‘alahum ka ‘asfin ma’kūl 5} * [Sūratul Fīl: 1 - 5].

Alaye

1- {Alam tarọ kayfa fa‘ala Rọbbuka bi as’haabil fīl 1}: Ṣe o o wa mọ - irẹ ojiṣẹ- bi Oluwa rẹ ṣe ṣe Abrahatu ati awọn eeyan rẹ awọn eleerin nigba ti won fẹ wo ka‘bah?!

2- {Alam yaj‘al kaydahum fī tadlīl 2}: Ọlọhun ti sọ ìpètepèrò aburu wọn lati wo o di anu, ọwọ wọn ko si tun tẹ nkan ti wọn fẹ lati siju awọn eeyan kuro ni ka‘bah, ọwọ wọn ko si tẹ nkankan ninu rẹ.

3- {Wa arsala ‘alayhim tayran ’abābīl 3}: O si tun gbe awọn ẹyẹ kan dide si wọn ti wọn wa ba wọn nijọnijọ.

4- {Tarmīhim bi hijāratin min sijjīl 4}: Ti wọn n ju wọn ni oko lati ara amọ̀ ti o le bii òkúta.

5- {Fa ja‘alahum ka ‘asfin ma’kūl 5}: Ọlọhun wa ṣe wọn gẹ́gẹ́ bí ewe irugbin ti awọn ẹranko ti jẹ ẹ ti o si tun ti tẹ ẹ mọlẹ.

Idahun- Sūratu Quraysh ati alaye rẹ:

"BismiLlāhir Rahmānir Rahīm"

"{Li ’īlāfi Quraysh 1 " "’Īlāfihim rihlatash shitā’i was sayf 2" " Fal ya‘budū robba hādhal bayt 3" "Allādhī ’at‘amahum min jū‘in wa āmanahum min khaof 4} [Sūratu Quraysh 1 - 4].

Alaye:

1- {Li ’īlāfi Quraysh 1}: Itumọ iyẹn ni nkan ti wọn ti ba saaba ni ṣiṣe irin-ajo ni asiko ọyẹ ati ni asiko ooru.

2- {’Īlāfihim rihlatash shitā’i was sayf 2}: Irin-ajo asiko ọyẹ lọ sí ilu Yemen, ati irin-ajo asiko ooru lọ sí ilu Shām lẹniti ọkan wọn balẹ.

3- {Fal ya‘budū robba hādhal bayt 3}: Ki wọn yaa maa sin Allāhu Oluwa ile abọwọ yii ni Oun nikan ṣoṣo, Ẹnití O ṣe irin-ajo yii ni irọrun fun wọn, ti wọn o si gbọdọ mu nkankan mọ Ọn ni orogun.

4- {Allādhī ’at‘amahum min jū‘in wa āmanahum min khaof 4}: Ẹniti maa n fun wọn ni jijẹ ninu ẹbi, ti si maa n fi ọkan wọn balẹ ninu ipaya, pẹlu nkan ti O fi si awọn ọkan awọn larubawa ni imaa gbe ile abọwọ naa tobi, ati imaa gbe awọn olugbe ibẹ tobi.

Idahun- Sūratul Mā‘ūn ati alaye rẹ:

"BismiLlāhir Rahmānir Rahīm"

"{Ara’aytal ladhī yukaddhibu bid dīn 1" "Fa dhālikal ladhī yaduhhul yatīm 2" "Walā yahuddu ‘alā ta‘āmil miskīn 3" "Fa waylun lil musọlliin 4" "Allādhīna hum ‘an sọlaatihim sāhūn 5" "Alladhīna hum yurā’ūn 6" "Wa yamna‘ūnal mā‘ūn 7}" "[Sūratul Mā‘ūn: 1 - 7].

Alaye:

1- {Ara’aytal ladhī yukaddhibu bid dīn 1}: Njẹ o mọ ẹni tí maa n pe ẹsan ti ọjọ Igbedide ni irọ.

2- {Fa dhālikal ladhī yaduhhul yatīm 2}: Oun ni ẹni naa ti maa n fi agbara le ọmọ orukan danu kuro nibi gbigbọ bukaata rẹ.

3- {Walā yahuddu ‘alā ta‘āmil miskīn 3}: Ko si ki n ṣe ẹmi rẹ ni ojukokoro, ko si tun ki n ṣe ẹlomiran ni ojukokoro lori fifun alaini ni ounjẹ.

4- {Fa waylun lil musalliin 4}: Nitori naa iparun ati iya ko maa bẹ fun awọn kirunkirun.

5- {Allādhīna hum ‘an salaatihim sāhūn 5}: Awọn ti wọn maa n gbagbera kuro nibi Irun wọn, ti wọn o si ki n bikita pẹlu rẹ titi ti asiko rẹ o fi lọ.

6- {Alladhīna hum yurā’ūn 6}: Awọn ti wọn maa n ṣe ṣekarimi pẹlu Irun wọn ati awọn iṣẹ wọn, wọn o si ki n mọ iṣẹ kanga fun Ọlọhun.

7- {Wa yamna‘ūnal mā‘ūn 7}: Wọn o si maa kọ lati ṣe iranlọwọ fun ẹni tí o yatọ si wọn pẹlu nkan ti ko si inira kankan nibi ṣiṣe iranlọwọ pẹlu rẹ.

Idahun- Sūratul Kaothar ati alaye rẹ:

" BismiLlāhir Rahmānir Rahīm "

{Innā a‘taynākal kaothar 1 " " Fa salli li robbika wanhar 2 " " Inna shāni’aka huwal ’abtar 3} " [Suuratul-Kawthar: 1-3].

Alaye

1- {Innā a‘taynākal kaothar 1}: Dajudaju Awa ni A fun ọ - irẹ Ojiṣẹ - ni oore ti o pọ, ninu rẹ naa si ni abata Kaothar ninu al-Jannah.

2- {Fa salli li robbika wanhar 2}: Nitori naa dúpẹ́ fun Ọlọhun rẹ lori idẹra yii, pẹlu ki o kirun fun Un ki o si pa ẹran fun Un ni Oun nikan ṣoṣo, yatọ si nkan ti awọn ọṣẹbọ maa n ṣe nibi imaa wa asunmọ awọn oriṣa wọn pẹlu pipa nkan fun wọn.

3- {Inna shāni’aka huwal ’abtar 3}: Dajudaju ẹniti ba n binu rẹ (korira rẹ) oun ni ẹniti o ja kuro nibi gbogbo daadaa, ẹni igbagbe ti o ṣe wipe ti wọn ba ranti rẹ wọn o ranti rẹ pẹlu aburu ni.

Idahun- Sūratul Kāfirūn ati alaye rẹ:

"BismiLlāhir Rahmānir Rahīm"

"{Qul yā ayyuhal kāfirūn 1" "Lā a‘budu mā ta‘budūn 2" "Walā ’antum ‘ābidūna mā a‘budu 3" "Walā anā ‘ābidun mā ‘abadtum 4" "Walā ’antum ‘ābidūna mā a‘budu 5" "Lakum dīnukum waliya dīni 6}" [Suuratul-Kafirun: 1-6].

Alaye

1- {Qul yā ayyuhal kāfirūn 1}: Sọ - irẹ Ojiṣẹ - pe mo pe ẹyin ti ẹ ṣe aigbagbọ pẹlu Ọlọhun.

2- {Lā a‘budu mā ta‘budūn 2}: Mi o nii sin nkan ti ẹ n sin ni awọn oriṣa lọwọlọwọ báyìí ati ni ọjọ iwaju.

3- {Walā ’antum ‘ābidūna mā a‘budu 3}: Ati pe ẹyin o nii sin nkan ti emi n sin, Oun naa ni Allāhu ni Oun nikan ṣoṣo.

4- {Walā anā ‘ābidun mā ‘abadtum 4}: Ati pe emi o nii sin nkan ti ẹ n sin ni awọn oriṣa.

5- {Walā ’antum ‘ābidūna mā a‘budu 5}: Ati pe ẹyin o nii sin nkan ti emi n sin, Oun naa ni Allāhu ni Oun nikan ṣoṣo.

6- {Lakum dīnukum waliya dīni 6}: Ti yin ni ẹsin yin ti ẹ da silẹ funra yin, temi naa si ni ẹsin mi ti Ọlọhun sọkalẹ fun mi.

Idahun- Sūratun Nasr ati alaye rẹ:

"BismiLlāhir Rahmānir Rahīm"

"{Idhā jā’a nasrul Lāhi wal fath 1" "Wa ra’aytan nāsa yadkhulūna fī dīnil Lāhi afwājā 2" "Fa sabbih bi hamdi rabbika wastagfirhu innahu kāna tawwābā 3}" "[Sūratun Nasri: 1 - 3]"

Alaye:

3- {Idhā jā’a nasrul Lāhi wal fath 1}: Ti aranse Ọlọhun ba ti de fun ẹsin rẹ - irẹ Ojiṣẹ -, ati fífún un ní agbára, ti ṣiṣi Mẹka si ṣẹlẹ.

2- {Wa ra’aytan nāsa yadkhulūna fī dīnil Lāhi afwājā 2}: Wàá ri awọn eeyan ti wọn o maa wọ inu Isilaamu ni ikọ kan lẹyin ikọ miran.

3- {Fa sabbih bi hamdi rabbika wastagfirhu innahu kāna tawwābā 3}: Lọ mọ wipe dajudaju iyẹn ami ipari iṣẹ ti wọn tori rẹ gbe ọ dide ni, nitori naa ṣe afọmọ pẹlu fifi ẹyin fun Oluwa rẹ, ki o fi wa aforijin lọdọ rẹ, dajudaju Oun ni Olugba-tuuba ti maa n gba tuuba awọn ẹrusin Rẹ, ti si tun maa n ṣe aforijin fun wọn.

Idahun- Sūratul Masad ati alaye rẹ:

"BismiLlāhir Rahmānir Rahīm"

{Tabbat yadā abī lahabin wa tabba 1" "Mā agnā ‘anhu māluhu wa mā kasaba 2" "Sa yaslaa nāran dhāta lahab 3" "Wamra’atuhu hammālatal hatab 4" "Fī jīdihā hablun min masad 5} "[Sūratul Masad: 1 - 5]"

Alaye

1- {Tabbat yadā abī lahabin wa tabba 1}: Ọwọ mejeeji ọmọ-ìyá baba Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tii ṣe Abu Lahabi ọmọ Abdul Muttalib ti p'ofo latari ipofo iṣẹ rẹ, nitori pe o maa n fi suta kan Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, nitori naa wahala rẹ ja si ofo.

2- {Mā agnā ‘anhu māluhu wa mā kasaba 2}: Ki ni nkan ti dukia ati ọmọ rẹ fi ṣe e ni anfaani? Wọn o lee ti iya danu fun un, bẹẹ si ni wọn o lee fa ikẹ wa fun un.

3- {Sa yaslaa nāran dhāta lahab 3}: Yio si wọ ina eléjò fòfò, ti yoo maa fojú winá ooru rẹ.

4- {Wamra’atuhu hammālatal hatab 4}: Iyawo rẹ Ummu Jamīl naa o wọ ọ (ina), ẹniti o ṣe wipe o maa n ni Anabi lara pẹlu dida ẹgun si oju-ọna rẹ.

5- {Fī jīdihā hablun min masad 5}: Okun kan ti wọn lọ yanjú (daadaa) wa ni orun rẹ ti wọn o fi wọ ọ lọ si inu ina.

Idahun- Sūratul Ikhlās ati alaye rẹ:

"BismiLlāhir Rahmānir Rahīm"

"{Qul Uwa Allāhu Ahad 1" "Allāhus Sọmad 2" "Lam yalid wa lam yūlad 3" "Wa lam yakun lahu kufwan ahad}" "[Sūratul Ikhlās: 1 - 4]"

Alaye

1- {Qul Uwa Allāhu Ahad 1}: Sọ - irẹ Ojiṣẹ -: Oun ni Ẹniti ijọsin tọ si, ko si ẹlomiran ti ijọsin tọ si yatọ si I.

2- {Allāhus Sọmad 2}: Itumọ rẹ ni pe: Ọdọ Rẹ ni wọn maa n gbe awọn bukaata awọn ẹda lọ.

3- {Lam yalid wa lam yūlad}: Ko si ọmọ fun Un ko si si baba (mimọ n bẹ fun Un).

4- {Wa lam yakun lahu kufwan ahad 4}: Ko si ẹniti o jọ ọ ninu awọn ẹda Rẹ.

Idahun- Sūratul Falaq ati alaye rẹ:

"BismiLlāhir Rahmānir Rahīm"

"{Qul a‘ūdhu bi robbil falaq 1" "Min sharri mā khalaqa 2" "Wa min sharri gāsiqin idhā waqaba 3" "Wa min sharrin naffāthāti fil ‘uqad 4" "Wa min sharri hāsidin idhā hasada 5}" "[Sūratul Falaq: 1 - 5]"

Alaye

1- {Qul a‘ūdhu bi robbil falaqi 1}: Sọ pe - irẹ Ojiṣẹ - mọ wa iṣọra pẹlu Ọba owurọ, mo si wa ààbò pẹlu Rẹ.

2- {Min sharri mā khalaqa 2}: Nibi aburu nkan ti maa n fi suta kan eeyan ninu awọn ẹda Rẹ.

3- {Wa min sharri gāsiqin idhā waqaba 3}: Mo si tun wa isadi pẹlu Ọlọhun kuro nibi awọn aburu ti maa n han ni oru lati ọwọ awọn ẹranko ati awọn ole.

4- {Wa min sharrin naffāthāti fil ‘uqad 4}: Mo si tun dirọ mọ Ọn kuro nibi aburu àwọn opindan lóbìnrin ti wọn maa n fẹ atẹgun tuẹtuẹ si inu awọn koko.

5- {Wa min sharri hāsidin idhā hasada 5}: Ati kuro nibi aburu oni keeta ti maa n binu wọn, nígbà tí o ba ṣe keeta wọn nibi nkan ti Ọlọhun fi ta wọn lọrẹ ninu idẹra, ti o n fẹ ki o yẹ kuro lọdọ wọn, ati ki aburu o ṣẹlẹ si wọn.

Idahun- Sūratun Nās ati alaye rẹ:

"BismiLlāhir Rahmānir Rahīm"

"{Qul a‘ūdhu bi robbin nās 1" "Malikin nās 2" "Ilāhin nās 3" "Min sharril waswāsil khannās 4" "Alladhī yuwaswisu fī suduurin nās 5" "Minal jinnati wan nās 6}" "[Sūratun Nās: 1 - 6]"

Alaye

1- {Qul a‘ūdhu bi robbin nās 1}: Sọ- irẹ ojiṣẹ - pe: Mo wa isadi pẹlu Ọba awọn ènìyàn, mo si tun wa aabo pẹlu Rẹ̀.

2- {Malikin nās 2}: O maa n ṣe nkan ti o ba wu u si wọn, ko si olukapa miran fun wọn yatọ si I.

3- {Ilāhin nās 3}: Ẹni tí wọn o maa jọsin fun lododo ni I, ti ko si si ẹni ti ìjọsìn tọ si fun wọn yàtọ̀ si I.

4- {Min sharril waswāsil khannās 4}: Kuro nibi aburu shaytān ti o maa n ju royiroyi rẹ si awọn eeyan.

5- {Alladhī yuwaswisu fī suduurin nās 5}: O maa n ju royiroyi rẹ si ọkan awọn ọmọniyan.

6- {Minal jinnati wan nās 6}: Ìtumọ̀ rẹ ni pé: Ẹniti maa n ko royiroyi báni le jẹ ninu awọn eeyan, o si le jẹ ninu awọn alujannu.