"Abala imọ agboye ẹṣin "

"Imọra: Oun ni gbigbe ẹgbin ti a ko le fi ojú ri, ati ẹgbin ti a le fi ojú ri"

"Mimọ ẹgbin ti a le fi ojú ri: Oun ni ki musulumi mu nnkan ti o wa ni ara rẹ ninu ẹgbin kuro, tabi to wa ni aṣọ rẹ, tabi to wa lori ilẹ ati aye ti o fẹ kirun nibẹ. "

"Mimọ ẹgbin ti a ko le fi ojú ri: Oun maa jẹ pẹlu aluwala tabi iwẹ, pẹlu omi ti o mọ tabi imọra oni erupẹ fun ẹni ti ko ri omi, tabi ti lilo ẹ ni i lara. "

"Idahun- pẹlu fifọ ọ pẹlu omi titi o fi maa mọ "

"-Sugbọn nnkan ti aja ba ti ẹnu bọ; a maa fọ ọ ni ẹẹmeje ti àkọ́kọ́ maa jẹ pẹlu erupẹ. "

"Anabi -ki ikẹ ati ọla maa ba a- sọ pe: “Ti musulumi ba ṣe aluwala, tabi olugbagbọ, ti o wa fọ oju rẹ; gbogbo ẹṣẹ ti o fi oju rẹ wo a jade pọ mọ omi, tabi pẹlu ekikan omi to kẹyin, ti o ba fọ ọwọ rẹ mejeeji; gbogbo ẹṣẹ ti o fi ọwọ rẹ mejeeji gbamu a jade pọ mọ omi, tabi pẹlu ekikan omi to kẹyin, ti o ba fọ ẹsẹ rẹ mejeeji; gbogbo ẹṣẹ ti o fi ẹsẹ rẹ mejeeji rin lọ sibẹ a jade pọ mọ omi, tabi pẹlu ekikan omi to kẹyin, titi yoo fi jade ni ẹni ti o mọ kuro nibi awọn ẹṣẹ” Muslim ni o gba a wa.

"Idahun- fifọ ọwọ lẹẹmẹta "

"Waa fi omi yọ ẹnu, waa si fa omi si imu, waa si fin omi si ita lẹẹmẹta."

AL-MADMADỌ ni: Fífi omi si ẹnu, ati titu u sita"

AL-ISTINSHAAQ: Fífa omi pẹlu atẹgun lọ si inu imu pẹlu ọwọ ọtun rẹ."

AL-ISTINTHAAR: Oun ni mimu omi jade lati inu imu lẹyin fifa a simu pẹlu ọwọ osi.

"Lẹyin naa ni fifọ oju lẹẹmẹta. "

"Lẹyin naa ni fifọ ọwọ mejeeji titi de igunpa mejeeji lẹẹmẹta"

"Lẹyin naa ni pipa ori lọ si iwaju pẹlu ọwọ rẹ mejeeji ati lọ si ẹyin, waa si pa eti mejeeji."

"Lẹyin naa waa fọ ẹsẹ rẹ mejeeji titi de kokosẹ mejeeji lẹẹmẹta "

"Eleyii ni eyi ti o pe julọ, iyẹn si fi ẹsẹ rinlẹ lati ọdọ Anabi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ninu awọn hadisi ninu Bukhari ati Muslim, ti awọn mejeeji gba a wa lati ọdọ Uthman ati Abdulahi Bn Zaid ati awọn to yatọ si awọn mejeeji, " O tun fi ẹsẹ rinlẹ bakannaa lati ọdọ rẹ ninu Bukhari ati ẹni ti o yatọ si i pe o ṣe aluwala ni ẹyọ kọọkan, ati pe o ṣe e ni ẹẹmeji meji pẹlu itumọ pe: O n fọ gbogbo oríkèé kọọkan ninu awọn oríkèé aluwala lẹẹkan, tabi lẹẹmeji. "

"Idahun- Oun ni eyi ti aluwala musulumi ko nii ni alaafia ti o ba gbe ẹyọkan ju silẹ ninu ẹ. "

"1- Fifọ oju ti yiyọ ẹnu ati fifa omi si imu n bẹ ninu ẹ. "

"2- Fifọ ọwọ mejeeji titi de igunpa mejeeji. "

"3- Pipa ori ti eti mejeeji n bẹ ninu ẹ

"4- Fifọ ẹsẹ mejeeji titi de kokosẹ mejeeji. "

"5- Tito tẹle ara wọn laarin awọn oríkèé, pẹlu pe ki o fọ oju, lẹyin naa ọwọ mejeeji, lẹyin naa pipa ori, lẹyin naa fifọ ẹsẹ mejeeji. "

"6- Isopọ: Oun ni ki aluwala waye ni asiko to sopọ mọ ara wọn, laisi alagata laarin asiko titi awọn oríkèé o fi gbẹ fun omi"

"- Gẹgẹ bii ki o ṣe idaji aluwala, ki o wa pari ẹ ni asiko miiran, aluwala rẹ o ni alaafia. "

"Idahun- awọn sunnah aluwala” ni eyi to jẹ pe ti o ba ṣe e, alekun ninu ẹsan o maa bẹ fun un, ti o ba gbe e ju silẹ; ko si ẹṣẹ fun un, aluwala rẹ ni alaafia. "

1- Didarukọ Ọlọhun: mo bẹrẹ pẹlu orukọ Ọlọhun.

2- Rirun pako

3- Fifọ ọwọ mejeeji.

4- Fifi ọwọ ya awọn ọmọnika

5- Fifọ oríkèé ara ẹlẹẹkeji ati ẹlẹẹkẹta.

6- Bibẹrẹ pẹlu ọtun

7- Ṣíṣe iranti lẹyin aluwala: Ash’hadu an laa ilaaha illal Loohu, wahdahuu laa shariika lahuu, wa ash’hadu anna Muhammadan abduhuu wa rosuuluhuu

8- Kiki irun rakah meji lẹyin rẹ.

Idahun- Ohun ti n jade lati oju ara mejeeji; oju ara ati oju idi bii itọ abi igbẹ abi iso.

Oorun ati yiya were ati hihunrira

Jijẹ ẹran rakunmi.

Gbigba oju-ara abi idi mu pẹlu ọwọ laisi gaga kankan.

Idahun- Tayammum: Oun ni lilo erupẹ abi nnkan miran ni ori ilẹ nigba ti ko ba si omi abi ti ko ba rọrùn lati lo o.

Idahun- Fifi oju ọwọ lu ilẹ ni lilu ẹẹkan ṣoṣo, ati pipa oju ati ẹyin ọwọ méjèèjì ni ẹẹkan ṣoṣo.

Idahun- Gbogbo ohun ti o ba ti le ba aluwala jẹ.

Ti wọn ba ri omi

Idahun- Khuffu mejeeji: Ni ohun ti wọn ba n wọ si ẹsẹ ti wọn ṣe latara awọ.

Ibọsẹ: Ohun ti wọn ba n wọ si ẹsẹ ti kii ṣe latara awọ.

Wọn ṣe e ni ofin lati pa awọn mejeeji ni ifirọpo fifọ ẹsẹ mejeeji.

Idahun - ṣiṣe idẹkun ati ṣiṣe ẹdẹ fun awọn ẹrusin, agaga julọ ni awọn asiko otutu ati ọyẹ ati irin-ajo, l'eyiti o ṣe wipe bibọ nkan ti o wa ni ẹsẹ mejeeji maa nira.

Idahun - 1 - ki o wọ abọsẹsẹ alawọ mejeeji lori imọra, itumọ rẹ ni lẹyin aluwala.

2- Ki abọsẹsẹ alawọ o jẹ nǹkan ti o mọ; nitori naa ko lẹ́tọ̀ọ́ ki o pa a lori ẹgbin.

3- Ki abọsẹsẹ alawọ jẹ nkan ti o bo aaye ti fifọ rẹ jẹ dandan nibi aluwala.

4- Ki pipa naa o jẹ laarin asiko ti a ti fi gbedeke sí, fun ẹniti o wa ni ile ti kii ṣe arinrin-ajo: Ọjọ kan ati oru kan, fun arìnrìn-àjò: Ọjọ mẹta pẹlu àwọn oru wọn.

Nípa iroyin (alaye) pipa abọsẹsẹ alawọ mejeeji oun naa ni: Ki o gbe awọn ọmọnika ọwọ rẹ mejeeji eleyii ti o ti tutu rẹ pẹlu omi lori awọn ọmọnika ẹsẹ rẹ mejeeji, lẹyin naa ki o wọ́ mejeeji lọ sibi ojúgun rẹ, yio pa ẹsẹ ọtun pẹlu ọwọ ọtún, yio si pa ẹsẹ osi pẹlu ọwọ osi, yio si ya awọn ọmọnika rẹ nígbà tí o ba n pa a, ko si nii paara rẹ.

Idahun-1- Pipari asiko pipa, nitori naa pipa abọsẹsẹ alawọ mejeeji o lẹ́tọ̀ọ́ lẹyin pipari asiko pipa tí a ti paala rẹ ninu sheriah (ofin ẹsin), ọjọ kan ati oru kan fun ẹniti n bẹ nile, ati ọjọ mẹta pẹlu awọn oru wọn fun arìnrìn-àjò.

2- Bibọ abọsẹsẹ alawọ mejeeji, ti ọmọnìyàn ba ti le bọ́ abọsẹsẹ alawọ mejeeji tabi ọkan ninu wọn lẹyin ti o ti pa a, pipa mejeeji ti bajẹ.

Idahun- Irun: Oun ni ṣiṣe ijọsin fun Ọlọhun pẹlu awọn ọrọ ati awọn iṣẹ ti wọn sa l'ẹsa, ti o bẹrẹ pẹlu ki kabara (gbigbe titobi fun Ọlọhun), ti o si pari pẹlu sí salamọ.

Idahun- Irun ọranyan lo jẹ lori gbogbo Musulumi.

Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: ﴾Dájúdájú ìrun kíkí jẹ́ ọ̀ran-anyàn tí A fi àkókò sí fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo 103﴿ [Sūratun Nisā‘i: 103].

Idahun- Gbigbe Irun ju silẹ iṣe keferi ni, Anabi - kí ikẹ ati ọla maa ba a - sọ pe: «Adehun ti n bẹ laarin wa ati laarin wọn (awọn keferi) ni Irun, ẹniti o ba wa gbe Irun ju silẹ ti di keferi». Ahmad ati Tirimidhi ati awọn mii yatọ si awọn mejeeji ni wọ́n gba a wa.

Idahun- Irun márùn-ún ni ni ojumọ (aarọ ati alẹ), Irun Al-fajri: Rakah meji, Irun Dhuri: Rakah mẹẹrin, Irun Asri: Rakah mẹẹrin, Irun Magrib: Rakah mẹta, Irun Ishai: Rakah mẹẹrin.

Idahun- 1- Isilaamu; ko (Irun) si nii ni alaafia lati ọdọ keferi.

2- Laakaye: ko si nii ni alaafia lati ọdọ weere.

3- Isẹ adayanri; ko si nii ni alaafia lati ọdọ ọmọde ti ko i tii le ṣe adayanri.

4- Aniyan.

5- Wíwọlé asiko.

6- Imọra nibi mímú ẹgbin aifojuri kúrò.

7- Imọra kuro nibi idọti (ẹgbin afojuri).

8- Bibo ihoho.

9- Didaju kọ Qiblah.

Idahun- Mẹrinla ni i, gẹ́gẹ́ bí o ṣe n bọ̀ yii:

Akọkọ rẹ: Diduro níbi Irun ọranyan fun ẹniti o ni ikapa.

Kabara imura, oun naa ni: “Allāhu Akbar”.

Kika Fātiah.

Itẹkọkọ, yio wàá na ẹyin rẹ tọọ ti yio si gbe ori rẹ si deedee rẹ.

Gbigbe ori kuro nibẹ (Itẹkọkọ).

Diduro dede.

Iforikanlẹ, gbigbe iwaju ori rẹ, ati imu rẹ, ati atẹlẹwọ rẹ mejeeji, ati orunkun rẹ mejeeji, ati awọn ọmọnika ẹsẹ rẹ mejeeji le aaye iforikanlẹ rẹ daadaa.

Gbigbe ori kúrò ni iforikanlẹ.

Ìjókòó laarin iforikanlẹ mejeeji.

Sunnah ni: Ki o jókòó ni ẹniti yio tẹ ẹsẹ osi rẹ silẹ, ti yio si na ẹsẹ ọtun rẹ duro, ti yio si da a kọ Qibla.

Ifarabalẹ, oun naa ni isinmi ara nibi gbogbo orígun ti o jẹ iṣẹ ṣiṣe.

Ataaya Igbẹyin.

Jíjókòó fun un (Ataaya igbẹyin).

Salamọ Mejeeji, oun naa ni ki o sọ ni ẹẹmeji pe: “As salāmu alaykum wa rahmotulloohi wa barakaatuhu”.

Tito awọn orígun tẹle ara wọn- gẹ́gẹ́ bí a ti wi - ti o ba wa fi orikanlẹ ṣíwájú ki o to rukuu lẹniti o mọ̀ọ́mọ̀ ṣe e; o (Irun) ti bajẹ, ti o ba wa jẹ ti igbagbe; o jẹ dandan fun un pipada lati lọ rukuu, lẹyin naa ki o wa fi ori kanlẹ.

Idahun- Awọn ọranyan Irun, mẹjọ ni, gẹ́gẹ́ bí o ṣe n bọ yii:

1- Awọn kabara yàtọ̀ si kabara imura.

2- Gbólóhùn: «Sami‘a Allāhu liman hamidahu» fun imaamu ati ẹniti n da Irun ki.

3- Gbolohun: «Robbanā wa lakal hamdu».

4- Gbolohun: «Subhāna robbiyal ‘adhīm» ni ẹẹkan ni rukuu .

5- Gbolohun: «Subhāna robbiyal ’a‘lā» ni ẹẹkan ni iforikanlẹ.

6- Gbolohun: «Robbi igfir lī» laarin iforikanlẹ mejeeji.

7- Ataaya àkọ́kọ́.

8- Jíjókòó fun ataaya àkọ́kọ́.

Idahun- Mọkanla ni i, gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe n bọ yii:

1- Gbolohun rẹ lẹyin kabara imura pe: «Subhānaka allāhummo wa bi hamdika, wa tabāraka ismuka,wa ta‘ālā jadduka, wa lā ilāha gayruka» wọn sì tun maa n pe e ni adua ìṣírun.

2- Wiwa iṣọra (Sisọ gbólóhùn "a‘udhu billāhi minash Shaytānir rajīm").

3- Ṣiṣe bismillahi.

4- Gbolohun: Āmīn.

5- Kika Sūrah lẹyin fātiha.

6- Gbigbe ohun soke pẹlu kika fun Imāmu.

7- Sisọ lẹyin gbolohun "Robbanā wa lakal hamdu" pe: «Mil’as Samāwāti, wa mil’al ardi, wa mil’a mā shita min shay'in ba‘d».

8- Ohun ti o ju ẹyọkan lọ nibi ṣiṣe afọmọ ni rukuu, ìyẹn tumọ si: Ṣiṣe afọmọ ẹlẹẹkeji ati ẹlẹẹkẹta, ati ohun ti o ba ju ìyẹn lọ.

9- Ohun ti o ju ẹyọkan lọ nibi ṣiṣe afọmọ iforikanlẹ.

10- Ohun ti o ba ju ẹyọkan lọ nibi gbolohun rẹ laarin iforikanlẹ mejeeji pe: "Robbi igfir lī".

11- Ṣíṣe asalaatu fun awọn ara-ile rẹ ki alaafia maa ba wọn, ati titọrọ alubarika fun un ati fun wọn, ati ṣiṣe adua lẹyin rẹ.

"Ẹlẹẹkẹrin: Sunna nibi awọn iṣẹ, ati pe wọn n pe e ni awọn iṣesi: "

"1- Gbigbe ọwọ mejeeji soke pẹlu ki kabara iwọ inu irun. "

"2- Ati nibi rukuu. "

"3- Ati nibi gbígbé orí kuro nibẹ. "

"4- Ati gbígbé mejeeji sílẹ̀ lẹyin iyẹn"

"5- Gbigbe ọtun lori osi. "

"6- Ki o maa wo ààyè ifi-ori-kanlẹ rẹ"

"7- Fífi àlàfo si àárín ẹsẹ rẹ mejeeji ni ẹni ti o duro"

8- Fifi ọwọ rẹ méjèèjì di orunkun rẹ méjèèjì mu ni ẹni tí ó máa ya àwọn ọmọnika nibi rukuu rẹ, ati títẹ́ ẹyin rẹ nibẹ, ati jijẹ ki ori rẹ ṣe déédéé ẹyin rẹ.

Fifi àwọn oríkèé iforikanlẹ kan ilẹ̀ daadaa, ki wọn si lé ilẹ̀ láìsí gàgá kankan.

"10- Mimu ọwọ́ rẹ mejeeji jina si ẹgbẹ rẹ mejeeji, ati ikun rẹ jina si itan rẹ mejeeji, ati itan rẹ mejeeji jina si ojugun rẹ mejeeji, ati fifi àlàfo si aarin orunkun rẹ mejeeji, ati ninaro ẹsẹ rẹ mejeeji, ati gbigbe awọn inu awọn ọmọ ika ọwọ rẹ mejeeji lori ilẹ ti o maa ya a, ati gbigbe ọwọ rẹ mejeeji si deede ejika rẹ mejeeji pẹlu titẹ awọn ọmọ ika rẹ ti o si maa lẹ àwọn ọmọ-ìka papọ. "

"11- Jíjókòó le ori ẹsẹ nibi ìjókòó laarin iforikanlẹ mejeeji, ati nibi ataya àkọ́kọ́, ati fifi idi jókòó nibi ẹlẹẹkeji. "

12- Gbígbé ọwọ méjèèjì lórí itan méjèèjì ni títẹ́ ti àwọn ọmọ-ika si maa wa ni lilẹ papọ láàrin iforikanlẹ méjèèjì, gẹgẹ bẹẹ naa ni nibi ataya, ṣùgbọ́n yoo ka ika kẹrin ati karùn-ún ko, yio ṣe atanpako pẹlu ìka aarin róbótó, yio maa fi ika keji tọka nibi iranti Ọlọhun. "

"13- Yio maa wo ọtun ati osi nibi sisalamọ rẹ. "

"Idahun- (1) gbigbe origun kan tabi majẹmu kan ju silẹ ninu awọn majẹmu irun. "

"(2) Mimọọmọ sọrọ. "

"(3) Jijẹ tabi mimu. "

"(4) Lilọ-bibọ to pọ to tẹle ara wọn. "

(5) Gbigbe ọranyan kan ninu awọn ọranyan irun ju silẹ ni ti amọọmọ ṣe. "

"Idahun- bi a ṣe n kirun: "

"1- Didojukọ qiblah pẹlu gbogbo ara rẹ, láìní yẹ̀ tabi yíjú. "

"2- Lẹyin naa yoo dàníyàn irun ti o fẹ ki pẹlu ọkan rẹ laini wi aniyan naa jáde. "

"3- Lẹyin naa yoo kabara iwọ irun, yio sọ pe: (Allahu Akbar), yio gbe ọwọ rẹ mejeeji soke titi de ejika rẹ mejeeji nibi kikabara. "

4- Lẹyin naa yio gbe atẹlẹwọ ọtun rẹ lori ẹyin atẹlẹwọ osi rẹ lori aya rẹ.

5- Lẹyin naa yio bẹrẹ Irun lẹniti yio maa sọ pe «Allāhumma bā‘id baynī wa bayna khatāyāya kamā bā‘adta baynal mashriq wal Magrib, allāhumma naqqinī min khatāyāya kamā yunnaqqa thaobul abyadu minad danas, allāhumma igsilnī min khatāyāya bil mā’i wath-thalji wal barad».

Tabi ki o sọ pe: «Subhānaka allāhumma wa bi amdika, wa tabāraka ismuka wa ta‘ālā jadduka, wa lā ilāha gayruka».

6- lẹyin naa yio wa iṣọra ti yio si maa sọ pe: «A‘ūdhu billāhi minash Shaytānir rajīm». 7- Lẹyin naa yio ṣe bismiLlāhi yio si ka Fātiha ti yio maa sọ pe: "BismiLlāhir Rahmānir Rahīm" 1 "Alhamdulillāhi robbil aalamiin" 2 "Ar-Rahmānir Rahīm" 3 "Māliki yaomid dīn" 4 "Iyyāka na‘budu wa iyyāka nasta‘īn" 5 "Ihdinas Sirātal mustaqiim" 6 "Sirātal Ladhīna an‘amta ‘alayhim gayril magdūbi ‘alayhim walad dālīn" 7 Sūratul Fātiha: 1-7.

Lẹyin naa yio sọ pe: (Āmīn) itumọ rẹ ni wipe: Irẹ Ọlọhun jẹ ipe.

8- Lẹyin naa yio ka eyikeyi ti o ba rọ ọ lọrun ninu Al-Qur'āni, yio si fa kika nkan gun nibi Irun Subhi".

9- Lẹyin naa yio rukuu, iyẹn tumọ si wipe: Yoo tẹ ẹyin rẹ lati gbe titobi fun Ọlọhun, yio si kabara nígbà tí o ba fẹ rukuu, ti yio si gbe ọwọ rẹ mejeeji si deedee ejika rẹ mejeeji. Àti pé sunnah ni: Ki o na ẹyin rẹ, ki o si fi ori rẹ ṣe deedee rẹ, yio si tun gbe ọwọ rẹ mejeeji le orunkun rẹ mejeeji l'ẹniti yio ya awọn ọmọnika ọwọ.

10- Yio si tun sọ nibi rukuu rẹ pe: «Subhāna robbiyal adhīm» ni ẹẹmẹta, ti o ba wa fi kun un pe: "Subhānaka allāhumma wa bi amdik, allāhumma igfir li», ìyẹn náà dáa.

11- Lẹyin naa yio gbe ori rẹ soke lati rukuu lẹniti yio maa sọ pe: «Sami‘a Llāhu liman hamidahu» ti yio si gbe ọwọ rẹ mejeeji si deedee ejika rẹ mejeeji. Ẹniti o jẹ ero ẹyin (ti n kirun lẹyin Imāmu) o nii sọ pe: «Sami‘a Llāhu liman hamidahu» bi ko ṣe pe yio sọ lati fi jirọ rẹ pe: «Rabbanā walakal amdu»

12- Lẹyin naa yio wa sọ lẹyin ti o ba ti gbe ori soke pe: «Rabbanā wa lakal amdu mil’as samāwāti wal ardi, wa mil’a mā shita min shay’in ba‘d».

13- Lẹyin naa yio ṣe iforikanlẹ àkọ́kọ́, yio waa maa sọ nígbà tí o ba fẹ fi orikanlẹ rẹ pe: “Allāhu Akbar” ti yio si fi oríkèé ara meje kanlẹ: Iwaju ori ati imu, atẹlẹwọ mejeeji, orunkun mejeeji, ati awọn ọmọnika ẹsẹ mejeeji, yio si gbe apa rẹ mejeeji jina si ẹgbẹ rẹ, ko si nii tẹ apa rẹ mejeeji silẹ, ti yio si tun da oju awọn ọmọnika ẹsẹ rẹ mejeeji kọ Qibla.

14- Yio waa maa sọ ni iforikanlẹ pe: «Subhāna robbiyal a’lā» ni ẹẹmẹta, ti o ba si tun fi kun un pe: «Subhānaka allāhumma robbāna wa bi amdika, allāhumma igfir lii» o daa.

15- Lẹyin naa yoo gbe ori soke lati iforikanlẹ lẹniti yio maa sọ pe: “Allāhu Akbar”.

16- Lẹyin naa yio jókòó laarin iforikanlẹ mejeeji lori ẹsẹ osi rẹ ti yio si na ẹsẹ ọtun rẹ, ti yio si gbe ọwọ ọtun rẹ si eti itan rẹ ọtun ti o tẹle orunkun, yio waa ka ìka oruka-yẹmi ati kurumbete kò, yio waa na ìka odun-unlabẹ rẹ soke ti yio si maa mi in nibi adua, ti yio si fi eti atampako rẹ ko eti ogajuwọnlọ gẹ́gẹ́ bíi òrùka róbótó, yio waa gbe ọwọ́ rẹ osi lori eti itan òsì rẹ ti o sunmọ orunkun ni ẹni tí yio tẹ́ awọn ọmọnika rẹ silẹ.

17- Yio si tun sọ nibi ìjókòó rẹ laarin iforikanlẹ mejeeji pe: «Robbi igfir lī, warhamnī, wahdinī, warzuqnī, wajburnī, wa ‘āfinī».

18- Lẹyin naa yio ṣe iforikanlẹ ẹlẹẹkeji gẹgẹ bii àkọ́kọ́ nibi nkan ti wọn n sọ ti wọn si maa n ṣe nibẹ, yio si kabara nibi iforikanlẹ rẹ.

19- Lẹyin naa yio dide nibi iforikanlẹ ẹlẹẹkeji lẹniti yio maa sọ pe: «Allāhu Akbar» yio si ki rakah ẹlẹẹkeji bíi àkọ́kọ́ nibi nkan ti wọn n sọ ti wọn si maa n ṣe nibẹ, ṣùgbọ́n ko nii sọ adua iṣirun nibẹ.

20- Lẹyin naa yio jókòó ti o ba ti pari raka‘ ẹlẹẹkeji lẹniti yio maa sọ pe: «Allāhu Akbar», yio si tun jókòó gẹgẹ bi o ṣe jókòó laarin iforikanlẹ mejeeji gẹlẹ.

21- Yio si ka ataaya nibi ìjókòó yii, ti yio maa sọ pe: At-Tahiyyātu lillāh was sọlawātu wat Tọyyibāt, As-salaamu alayka ayyuhan nabiyyu warahmatulloohi wabarokaatuh, as’salāmu ‘alaynā wa ‘alā ‘ibādillāhis soolihiin, ’Ashhadu ’an lā ’ilāha ’illāLlāhu, wa ’ashhadu ’anna Muhammadan ‘abduhu wa rọsūluhu, allāhummọ solli ‘alā Muhammadin wa ‘alā āli Muhammadin, kamā sollayta ‘alā ’Ibrāhīm wa ‘alā āli ’Ibrāhim, ’innaka Hamīdun Majīd, wa bārik ‘alā Muhammadin wa ‘alā āli Muhammadin, kamā bārakta ‘alā ’Ibrāhīm wa ‘alā āli ’Ibrāhim, ’innaka Hamīdun Majīd. ’A‘ūdhu bil Lāhi min ‘adhābi jahannam, wa min ‘adhābil qobri, wa min fitnatil mahyā wal mamāti, wa min fitnatil masīhid dajjāl»

"Gbogbo kiki ti Ọlọhun ni, gbogbo Irun ati gbogbo dáadáa tí Ọlọhun ni, ọla Ọlọhun ki o maa ba ọ iwọ Anabi ati ikẹ Rẹ ati awọn oore Rẹ, ọla Ọlọhun ki o maa ba awa naa ati gbogbo awọn ẹrusin Ọlọhun ti wọn jẹ ẹni ire, mo jẹri wipe ki ẹnití ìjọsìn ododo tọ sí ayaafi Allōhu, mo sì tun jẹri wipe Muhammad ẹru Rẹ ni òjíṣẹ Rẹ sì ni pẹlu, Iwọ Oluwa wa ṣe ikẹ fún Anabi Muhammad, ati awọn ara ile Anabi Muhammad, gẹgẹbi O ṣe ṣe ikẹ fún Anabi Ibrōhēm ati awọn ara ile Anabi Ibrōhēm dajudaju Irẹ ni Ọba ẹlẹyin Ọba ti o tobi, Oluwa wa ṣe Ìbùkún fún Anabi Muhammad ati awọn ara ile Anabi Muhammad, gẹgẹbi O ṣe ṣe Ìbùkún fún Anabi Ibrōhēm ati awọn ara ile Anabi Ibrōhēm, dajudaju Irẹ ni Ọba ẹlẹyin Ọba ti o tobi" Lẹyin naa yio wa kepe Oluwa rẹ pẹlu nkan ti o ba fẹ ninu oore aye ati ti ọjọ ikẹhin.

22- Lẹyin naa yio waa salamọ si ọtun rẹ l'ẹniti yio maa sọ pe: «As Salāmu alaykum wa rahmotulloohi», ati osi rẹ bákannáà.

23- Ti Irun ba wa jẹ olopoo mẹta tabi mẹẹrin; yio duro nibi ipari ataaya àkọ́kọ́, oun naa ni: «’Ashhadu ’an lā ’ilāha ’illāLlāhu, wa ’ashhadu ’anna Muhammadan ‘abduhu wa rọsūluhu»

24- Lẹyin naa yio waa dide duro l'ẹniti yio maa sọ pe: «Allāhu Akbar», ti yio si gbe ọwọ rẹ mejeeji si deedee ejika rẹ mejeeji nígbà náà.

25- Lẹyin naa yio ki èyí tí o ṣẹku nibi Irun rẹ lori iroyin rakah ẹlẹẹkeji, ṣùgbọ́n Fātiah nikan ni yio ka.

26- Lẹyin naa yio jókòó ni ìjókòó tawarruk, ti yio gbe ẹsẹ ọtun rẹ soke, yio si yọ ẹsẹ osi rẹ jade labẹ ojugun rẹ ọtun, ti yio si fi idi rẹ le'lẹ dáadáa, yio waa gbe ọwọ rẹ mejeeji lori itan rẹ mejeeji lori iroyin bi o ṣe gbe e nibi ataaya àkọ́kọ́.

27- Yio waa ka gbogbo ataaya nibi ìjókòó yii.

28- Lẹyin naa yio wàá salamọ si ọtun rẹ l'ẹniti yio maa sọ pe:: «As Salāmu alaykum wa rahmotulloohi», ati osi rẹ bákannáà.

Idahun- «Astagfirullāha» ni ẹẹmẹta.

«Allāhummọ ’Antas Salām, wa minKas salām, tabārakTa, yā Dhal jalāli wal ikrām».

“Laa ilaaha illa laah, Wah'dahu laa shariika lahu, lahul Mulku wa lahul Hamdu Wa uwa ala kulli shaein Qodiir,Allahuma la maaniha lima A'tayta Wa la mu'tiya lima mana'ta wa la yan'fahu zal jaddi Minkal jaddu” (Ko si eniti ijosin to si ayafi Allah nikan, ko si orogun fun Un, ti E ni ola se, atipe ti E ni eyin se, atipe O je alagbara lori gbogbo nkan, Ire Oluwa, ko si oludena fun nkan ti O ba fun ni, atipe ko si olufunni ni ohun ti O ba ko funni atipe oro kole wulo fun oloro ni odo Re).

«Lā ’ilāha ’illāLlāhu wahdahu lā sharīka lahu, lahul mulku wa lahul amdu, wa huwa ‘alā kulli shay’in qodīr, lā haola walā quwwata illā bilLāh, lā ’ilāha ’illāLlāhu, walā na‘budu illā Iyyāhu, laHun ni‘matu wa laHul fadlu wa laHuth thanā’ul hasan, lā ’ilāha ’illāLlāhu mukhlisiina laHud dīn wa lao karihal kāfirūn».

«Subhānallāhi» ni igba mẹtalelọgbọn.

«Alhamdulillāhi» ni igba mẹtalelọgbọn.

«Allāhu Akbar» ni igba mẹtalelọgbọn.

Lẹyin naa yio sọ ni ipari ọgọ́rùn-ún pe: «Lā ilāha illāLlāhu wahdahu lā sharīka lahu, lahul mulku wa lahul amdu, wa huwa ‘alā kulli shay’in qodīr».

Yio ka Sūratul Ikhlās (qul Uwa Allāhu Ahad) ati Al-Mu‘awwidhāt (qul a‘ūdhu bi robbil falaqi ati qul a‘ūdhu bi robbin nās) ni ẹẹmẹta lẹyin Irun Al-fajri ati Irun Magrib, ati ni ẹẹkan lẹyin awọn Irun yoku.

Yio si tun ka āyatal qursiyyu ni ẹẹkan.

Idahun- Raka‘a meji ṣíwájú Al-fajri.

Raka‘a mẹẹrin ṣíwájú irun aila.

Raka‘a meji lẹyin irun aila.

Raka‘a meji lẹyin Magrib.

Raka‘a meji lẹyin Ishai.

Ọla rẹ: Anabi sọ pe: «Ẹniti o ba ki Raka‘a akigbọrẹ mejila ni ojumọ (aarọ ati alẹ) Ọlọhun maa kọ ile kan fun un ninu ọgba alujanna» Muslim ati Ahmad ati ẹlomiran yatọ si awọn mejeeji ni wọn gba a wa.

Idahun- Ọjọ Jumu‘ah, Anabi - ki ikẹ ati ọla maa ba a - sọ pe: «Dajudaju ninu awọn ọjọ yin to daa julọ ni ọjọ Jumu‘ah, ninu ẹ ni wọn da Ādam, ninu ẹ ni wọn gba ẹmi rẹ, ninu ẹ feere fifun o ti waye, ninu ẹ ni kiku (gbogbo ẹda) o ti waye; nitori naa ẹ pọ ni ṣiṣe assalātu fun mi ninu ẹ; nítorí pé dajudaju wọn yio maa fi assalātu yin han mi» O sọ pe: Wọn sọ pe irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, bawo ni wọn o ṣe maa fi awọn assalātu wa han ọ ti o si jẹ wipe o ti kẹfun - nkan ti wọn n sọ ni pe o ti jẹra - o wa sọ pe: «Dajudaju Ọlọhun - ti O biyi ti O si tun gbọnngbọn - ti ṣe awọn ara awọn Anabi Rẹ ni eewọ fun ilẹ». Abu Daūd ati ẹlomiran yatọ si i ni wọ́n gba a wa.

Ọranyan ojulowo ni i lori gbogbo Musulumi ti o jẹ ọkunrin ti o ti balaga ti o ni laakaye ti o n bẹ ninu ilu (ti kii ṣe arinrin-ajo).

Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: ﴾Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí wọ́n bá pe ìrun ní ọjọ́ Jum‘ah, ẹ yára lọ síbi ìrántí Allāhu, kí ẹ sì pa kátà-kárà tì. Ìyẹn lóore jùlọ fun yín tí ẹ bá mọ̀.9﴿ [Sūratul Kāfirūn: 9].

Idahun- Onka Raka‘a Irun Jumu‘a meji ni, ti Imāmu o si gbe ohun s'oke nibẹ, l'eyi ti o ṣe wipe khutubah meji ti a ti mọ o ṣaaju rẹ.

"Idahun- Pipa irun ọjọ jimọh jẹ o lẹ́tọ̀ọ́ afi pẹlu idi kan to jẹ ti sharia, o wa lati ọdọ Anabi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe: " “Ẹnikẹni ti o ba gbe irun ọjọ jimọh mẹta ju silẹ ni ti ailakakun pẹlu ẹ; Ọlọhun maa fi edidi di ọkan rẹ”. " Abu Daud ati ẹni ti o yatọ si i ni wọn gba a wa"

Idahun

"1- Wiwẹ "

"2- Lilo lọfinda"

"3- Wiwọ eyi to daa julọ ninu aṣọ"

"4- Titete lọ si mọsalasi"

"5- Pipọ ni ṣíṣe asalaatu fun Anabi -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- "

"6- Kika suratul kahf."

"7- Lilọ si mọsalasi ni ẹni ti o n rin"

"8- Wiwa asiko gbigba adura."

"Idahun- Lati ọdọ Abdulahi ọmọ Umar -ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji-, pe Ojiṣẹ Ọlọhun -ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: " “Irun janmọọn ni ọla ju irun adaki lọ pẹlu ipò mẹtadinlọgbọn”. " Muslim ni o gba a wa.

"Idahun- oun ni ki ọkàn wà nibẹ, ki ara o sì balẹ.

Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: {Dájúdájú àwọn onígbàgbọ́ òdodo ti jèrè 1 " "{Àwọn t’ó ń páyà (Allāhu) nínú ìrun wọn 2} "[Surah Al-Mu’minûn: 1, 2]"

"Idahun- oun ni iwọ kan to jẹ dandan nibi dúkìá kan pàtó, fun àwọn kan pàtó, ni asiko kan pàtó.

Origun kan ni in ninu awọn origun Isilaamu, saara ti o jẹ ọranyan si tun ni in ti wọn gbọdọ yọ lọwọ eeyan abọrọ ti wọn o si ko o fun alaini.

Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ẹ yọ Zakāh. [Suuratul-Baqarah: 43].

Idahun: Oun yatọ si Zakah, gẹgẹ bii: Ṣíṣe saara pẹlu èyíkéyìí nǹkan si àwọn ọna oore ni eyikeyii akoko.

Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: {Ẹ nawo si oju ọna Ọlọhun}. [Suuratul-Baqarah: 195].

Idahun: Oun ni ṣiṣe ijọsin fun Ọlọhun pẹlu kikoraro kuro nibi ohun ti o le ba aawẹ jẹ lati igba ti alufajari ba ti yọ titi di igba ti oorun yoo fi wọ pẹlu dida aniyan, o si ni iran meji:

Aawẹ ọranyan: Bii gbigba aawẹ oṣu Ramadan, o si jẹ origun kan ninu awọn origun Isilaamu.

Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, A ṣe ààwẹ̀ náà ní ọ̀ran-anyàn fun yín, gẹ́gẹ́ bí A ti ṣe é ní ọ̀ran-anyàn fún àwọn t’ó ṣíwájú yín, nítorí kí ẹ lè bẹ̀rù (Allāhu). 183 [Suuratul-Baqarah: 183].

Aawẹ ti kii ṣe ọranyan: Gẹ́gẹ́ bii gbigba aawẹ ọjọ aje ati ọjọbọ ni gbogbo ọsẹ, ati gbigba aawẹ ọjọ mẹta ni gbogbo oṣu, awọn ọjọ ti o si lọla ju ninu rẹ naa ni (13, 14, 15) ni gbogbo oṣu oju ọrun.

Idahun- Lati ọdọ Abu Hurairah (ki Ọlọhun yọnu si i), dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a) sọ pe: Ẹnikẹni ti o gba aawẹ Ramadan pẹlu igbagbọ ati ni ẹni tí ń rankan ẹsan lọdọ Ọlọhun; wọn yoo ṣe aforijin ohun ti o ti lọ ninu ẹṣẹ rẹ. Wọn fi ẹnu ko le e lori.

Idahun- Lati ọdọ Abu Sa'eed Al-Khud'riy (ki Ọlọhun yọnu si i) o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a) sọ pe: Ko si ẹru kankan ti yoo gba aawẹ ọjọ kan ni oju ọna Ọlọhun ayafi ki Ọlọhun titori rẹ gbe oju rẹ jina si ina ni dedee aadọrin ọdun Wọn fi ẹnu ko le e lori.

Itumọ “aadọrin Khareef”; iyẹn ni pe: Aadọrin ọdun.

Idahun- 1- Mimọọmọ jẹun ati mimọọmọ mu.

2- Mimọọmọ bi.

3- Kikuro ninu Isilaamu.

Idahun- 1- Yiyara ṣinu

2- Saari jijẹ ati lilọ ọ lara.

3- Nini alekun lori awọn iṣẹ rere ati ijọsin.

4- Ki alaawẹ sọ nigba ti wọn ba bu u pe: Alaawẹ ni mi.

5- Ṣiṣe adua nigba ti a ba fẹ ṣinu.

6- Fifi eso dabinu tutu abi gbigbẹ ṣinu, ti ko ba si; ni o too kan omi.

Idahun- Hajj: Oun ni jijọsin fun Ọlọhun Ọba ti O ga pẹlu ero lilọ si ile Rẹ abeewọ lati ṣe awọn iṣẹ kan pàtó ni asiko kan pàtó.

Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: {Allāhu ṣe àbẹ̀wò sí Ilé náà ní dandan fún àwọn ènìyàn, t’ó lágbára ọ̀nà tí ó máa gbà débẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàì gbàgbọ́,dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́rọ̀ tí kò bùkátà sí gbogbo ẹ̀dá. 97} [Suuratul Aal Im'raan: 97]

Idahun- 1 - Gbigbe aṣọ áràmí wọ.

2 - Diduro si oke arafa

3 – Tawaaful Ifaadọ.

4 - Sisa safa ati mar'wa

Idahun- Lati ọdọ Abu Huraira (ki Ọlọhun yọnu si i) o sọ pe: Ẹni tí o ba ṣe hajj nitori Ọlọhun ti ko ba iyawo rẹ sun oorun ìfẹ́, ti ko si dá ẹ̀ṣẹ̀; yoo pada gẹgẹ bi ọjọ ti iya Rẹ bi i. Bukhaari ati awọn ẹlomiran ni wọ́n gba a wa.

«Gẹgẹ bii ọjọ ti iya rẹ bi i»: itumọ rẹ ni pe lai ni ẹṣẹ kankan.

Idahun- ‘Umrah: Oun ni jijọsin fun Ọlọhun - ti ọla Rẹ ga - pẹlu gbigbero ile Rẹ abọwọ fun awọn iṣẹ kan ti wọn jẹ ẹsa ni eyikeyi akoko.

Idahun -1- Gbigbe Harami.

3- Rirọkirika ile Ọlọhun.

3- Sísá Safa ati Marwa.

Idahun- Oun naa ni nina igbiyanju ati ikapa si ibi titan Isilāmu ka ati dida aabo bo o ati awọn Musulumi, tabi biba ọta Isilaamu ati awọn Mùsùlùmí jagun.

Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pe: ﴾Kí ẹ sì fi àwọn dúkìá yín àti ẹ̀mí yin jagun fún ẹ̀sìn Allāhu. Ìyẹn lóore jùlọ fun yín tí ẹ bá mọ̀. 41﴿ [Suuratu At-Tawbah: 41].